Àwọn ara Ibadan yarí bí Mọgaji kan ṣe ti ọ̀pọ̀ ilé pa, wọ́n gbé ìfẹ̀hónúhàn lọ sí ọ́físì Gómínà

Aworan

Ni owurọ Ọjọbọ ni ọgọrọ awọn olugbe agbegbe ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ kọrajọpọ lati ṣe ifehonuhan lọ si ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ, to n bẹ ni agbegbe Agodi ni ilu Ibadan, lẹyin ti ọpọlọpọ wọn ti ibi iṣẹ de ni Ọjọru ti wọn si dede ba ọkanojọkan agadagodo lẹnu ọna ile wọn.

Iroyin ti wọn gbọ ni pe ọkan lara awọn Mọgaji ilẹ Ibadan ti wọn jọ n fa ọrọ ilẹ lo gbe igbesẹ naa. Onka ile ti Magaji naa si tipa le ni igba gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Họnọrebu Ọlatunde Kehinde to n ṣoju ẹkun idibo keji ni ijọba ibilẹ Akinyẹle lo jade si awọn olufẹhonuhan naa. O ni ori redio ni oun ti kọkọ gbọ iroyin wi pe Mọgaji kan ti ọpọlọpọ ile pa ni ijọba ibilẹ ti o n ṣoju fun, lai mọ wi pe ile iya oun gan wa lara awọn ile ti wọn ti pa.

O ni igbesẹ akọkọ ni lati kan si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa lati le wa ojutu si ọrọ naa nipa jijiroro pẹlu Kọmisana ajọ Ọlọpaa n’ipinlẹ Ọyọ.

Kehinde ni oun ko mọ Mọgaji to ṣiṣẹ naa, bẹẹ sini oun ko ni nọmba ẹrọ ilewọ rẹ, ṣugbọn oun yoo gbe igbesẹ lati rii pe ọrọ naa tẹnubodo.

Aworan

Awọn olugbe agbegbe naa to ba akọroyin wa sọrọ fi igbe ta wi pe ile ẹjọ kankan koba wọn da si ọrọ ilẹ ri de ibi ti ọrọ yoo ti pa wọn pọ pẹlu Mọgaji to n fi ọwọ sọya wi pe oun l’oun ni ilẹ gbogbo agbegbe naa.

Nigba ti wọn ko ọrọ naa de aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ke si Mọgaji naa lati gbọ tẹnu rẹ, alaye ti o si ṣe ni pe oun kan fi igbesẹ naa dẹru ba awọn olugbe agbegbe naa ni.

BBC Yoruba kan si ẹni ti wọn fi ẹsun kan, Mọgaji Wale Ọladọja ti o jẹ Mọgaji ile Akinṣọla n’ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ, alaye ti o ṣe ni wi pe ki oun to di Mọgaji ni ọrọ ilẹ naa ti wa nilẹ. O fi kun ọrọ rẹ wi pe ija ajogunba ni ija ilẹ naa to n bẹ ni agbegbe Labi ni ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ.

Mọgaji naa ni ilẹ baba awọn ni ilẹ agbegbe naa lati ilẹ wa, ki o to di pe awọn ọdaran kan bẹrẹ sini ta ilẹ naa fun ọpọpọlọ awọn olugbe to kọle wọn ibẹ titi di asiko yii.

Ọladọja ni pupọ awọn aṣiwaju ninu ẹbi awọn lo ti gbe igbesẹ lati gba aṣẹ ile ẹjọ ni igba marun un ọtọọtọ lori ọrọ yii, ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si. Eyii lo mu ki oun naa tun pa kun igbiyanju wọn lati gba ilẹ ati ẹtọ awọn baba wọn pada.

Aworan

O tẹsiwaju wi pe igbesẹ ti awọn gbe l’Ọjọru lo waye nipasẹ aṣẹ ile ẹjọ ati ajọṣepo awọn agbofinro. Lodi si iroyin to n lọ kaakiri wi pe wọn ti awọn eeyan mọle ni agbegbe naa, Magaji Ọladọja ni awọn ọgba ilẹ ti wọn ko tii kọlẹ si nikan ni awọn sọ agadagodo si ti awọn si fa maaki si ara awọn ile ti wọn kọ si ori ilẹ ti awọn eeyan si n gbe ni agbegbe naa.

Ọladọja ni, “Ọna abayọ si ọrọ to wa nilẹ yii ni ki a jọ joko yika tabili ki a si sọ asọyepọ nitori eniyan ṣaa ni gbogbo wa. Mo ti pe gbogbo wọn si ipade saaju asiko yii. Nigba ti ko wa loju ti awọn ẹbi wa ro pe boya mo ti gba nnkan kan lọwọ wọn ni mo fi n tẹ ọrọ yii ri, ni awa naa fi gba ile ẹjọ lọ.”

Aworan

O ni gbogbo awọn to ṣi ilẹ naa ta ni ile ẹjọ pe sita ti wọn si da wọn lẹbi ki to di pe ile ẹjọ fun idile to ni ilẹ naa ni aṣẹ lati lọ ṣe ohun ti o tọ.

Ohun ti Mogaji naa ati mọlẹbi rẹ si fẹ bayii ni asọyepo pẹlu awọn ti ofin ni wọn ra ilẹ lọna aitọ.

Ọladẹjọ ke si awọn to n ṣe ifẹhonuhan lati tẹwọ gba alaafia ati asọyepọ ki ọrọ naa le ni iyanju.

Bakan naa ni Magaji naa ṣe alaye wi pe ipade kan yoo waye lori ọrọ ilẹ naa l’ọjọ Aiku l’aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan.