Oke, Edema pè fún fífagilé ètò ìdìbò abẹ́lé gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlè Ondo

Olusola Oke ati Gbenga Edema

Oríṣun àwòrán, Olusola Oke/Facebook

Awọn oludije sipo Gomina ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ Oṣelu APC to waye nipinlẹ Ondo ti ṣapejuwe eto naa gẹgẹ bi eyi to kun fun ọpọlọpọ magomago ati fifi igba kan bokan ninu ti wọn si n kesi awọn alasẹ ẹgbẹ naa lati fagile eto idibo ọhun.

Ọkan lara awọn oludije naa Olugbenga Edema n’ilu Akure salaye pe igbimọ to dari eto naa ti Gomina Ipinlẹ Kogi Ahmed Usman Ododo saaju ni ko se ni ibamu pẹlu adehun rẹ.

Edema sọ pe awọn igbimọ naa ni wọn kọ lati ti pin awọn ohun elo idibo ni ọpọlọpọ wọọdu ti o yẹ ki eto idibo ti waye n’ilu Akure ti o si jẹ pe eto idibo ti n waye ni agbegbe Gusu ati Ariwa Ipinlẹ Ondo.

O sọ pe Akọwe igbimọ eto idibo naa, Sẹnẹtọ Omo-Agege ti kọkọ ni adehun pẹlu wọn pe deedee ago mefa owurọ ni wọn yoo pin awọn ohun elo sugbọn ìyàlẹ́nu nla lo jẹ fun wọn pe titi di ago mewaa wọn ko ri ohun elo idibo.

Edema sọ pe ki wọn fagile eto idibo naa ti wọn ko ba le se ohun ti o tọ.

Bakan naa, Oloye Olusola Oke ẹni ti Ogbeni Ogunleye Rotimi soju fun sọ pe wọn ko ko awọn ohun elo idibo wa si agbegbe rẹ eyi ti ko fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati dibo yan ẹni ti ọkan wọn n fẹ.

O ni wọn gbọdọ se ohun ti o tọ nitori aparo kan ko ga ju’kan lọ.

Ẹni o jẹ oluranlọwọ Oloye Oke lori ọrọ iroyin, Ojo Oyewamide ninu atejade sọ pe eto Idibo abẹle kankan ko waye nipinlẹ Ondo loni.

O ni ohun tí o waye ni gbogbo wọọdu 203 nipinlẹ ni o tako eto ijọba tiwantiwa.

Oyewamide sọ pe gbogbo awọn igbimọ ti o wa dari eto naa ni wọn jẹ ọrẹ timọtimọ si okan lara awọn oludije ti wọn si jọ ṣe wẹjẹ-wẹmu saaju eto idibo naa.

O sọ pe Oloye Oke ko tewo gba eto idibo naa nitori o tabuku ẹtọ awọn oludibo labẹ ofin, bẹẹni ko fi ẹgbẹ Oṣelu APC si ipo ti o dara lawujọ latari irufẹ eto idibo ti o waye.

Ondo APC Primaries: Gómìnà Aiyedatiwa ti dìbò ní wọ́ọ̀dù rẹ̀ n’íjọba ìbílẹ̀ Ilaje

Aworan gomina Lucky Aiyedatiwa

Gomina ipinlẹ Ondo, Orimisan Aiyedatiwa ti dibo tirẹ ninu eto idibo gomina abẹle ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ naa to waye lọjọ Abamẹta.

Woodu 4 n’ilu Obe-Nla nijọba ibilẹ Ilajẹ lagbegbe ori-omi nipinlẹ Ondo ni Aiyedatiwa ti dibo ọhun.

Ẹwẹ, gomina ti ṣapejuwe eto Ibo naa to n lọ lọwọ gẹgẹ bi eyi ti kosi wahala kankan nibẹ bi o ti wu ko mọ.

Aiyedatiwa ṣe afikun pe ifẹ awọn ara ilu ni yoo ṣe lẹyin eto idibo naa.

O ni akoko ti to fun agbegbe Ilaje lati ni gomina latari awọn ohun alumọni ti o sodo si agbegbe naa.

Aiyedatiwa sọ pe oun ni igbagbo pe didun lọsan yoo so leyin eto idibo abele naa.

Ètò ìdìbò abẹ́lé APC Ondo ń lọ lọ́wọ́, wo àwọn olùdíje sí ipò Gómìnà

Awon oludije sipo gomina ni egbe APC

Oríṣun àwòrán, Others

Lonii ni pupọ awọn olugbe ipinlẹ Ondo, paapa awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress yoo mọ oludije ti yoo soju wọn ninu eto idibo Gomina to n bọ.

Igbagbọ wa pe awọn ara ipinlẹ Ondo paapa awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu APC yoo tuyaya tuyaya jade lọ si awọn ibudo idibo ni ijọba ibilẹ kowa wọn nibi wọn yoo ti yan ẹni ti wọn fẹ soju ẹgbẹ naa gẹgẹ bii gomina ninu eto idibo gomina to n bọ.

Ẹwẹ, eyi ni awọn koko ọrọ to yẹ ko mọ nipa awọn oludije to gbe igba idibo naa

Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa

Aworan Luck Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Facebook

A bi Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa ni ọjọ Kejila oṣu kini ọdun 1965 n’ilu Obe-Nla nijọba ibilẹ Ilajẹ nipinlẹ Ondo.

Gomina Aiyedatiwa lọ ile ẹkọ Saint Peter’s UNA Obe Nla/Obe, to si se ile ẹkọ girama rẹ ni Ikosi High School, Ketu nipinlẹ Eko laarin 1982 sì 1986.

O gba iwe ẹri NCE ninu imọ Economics and Government ni Lagos State College of Education, Ijanikin nipinle Eko, lẹyin naa lo tesiwaju lọ fasiti Ipinlẹ Eko.

Aiyedatiwa tesiwaju lọ fasiti Liverpool nilẹ Geesi nibiti o ti gba iwe ẹri masters ni Business Administration.

Aiyedatiwa darapọ mọ eto oselu lọdun 2011 gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ Oṣelu ACN eyi to darapọ mọ ẹgbẹ miran lati da ẹgbẹ Oṣelu APC silẹ. O dije lati soju ijọba ibilẹ Ilajẹ /Ẹsẹ-Odo nile igbimọ asoju sofin ninu eto idibo ọdun 2015. Aiyedatiwa jẹ asoju Ipinlẹ Ondo ninu igbimọ ajọ to n bojuto agbagbe Niger Delta laarin ọdun 2018 sì 2019.

Wọn yan an gẹgẹ bi igbakeji Gomina Oluwarotimi Akeredolu ninu eto sipo Gomina Ipinlẹ Ondo lọdun 2020. Ni ọjọ kokanla oṣu kẹwa ni wọn dibo fun wọn wọle ni ibamu pẹlu ikede àjọ INEC.

Aiyedatiwa di Adele Gomina lasiko ti Akeredolu wa ni idubulẹ aisan nilẹ okeere. Ni ọjọ kẹta-din-lọgbọn oṣu kejila ọdun 2023 Gomina Akeredolu papoda wọn si burawọle fun Aiyedatiwa lọjọ kan naa.

Oluṣọla Oke

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Oloye Olusola Alexander Oke jẹ gbajugbaja Amofin ati Oloselu ti wọn bi lọjọ keje oṣu kẹrin ọdun 1965 n’ilu Ilowo nijọba ibilẹ Ilajẹ nipinlẹ Ondo.

Oloye Oke lọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ UNA Primary School ti O si pari rẹ ni Methodist primary school Ilepete lọdun 1973. O lọ ile ẹkọ girama ni Methodist Secondary Modern School Ilepete ti o si setan lọdun 1979.

O tẹsiwaju ni fasiti Obafemi Awolowo Ile-Ife lati kẹkọ nipa imọ ofin.

Olusola Oke soju ijọba ibilẹ Ilaje/Ẹsẹ-Odo nile igbimọ asoju sofin lọdun 1992. Wọn yan si igbimọ to n bojuto agbegbe Niger Delta NDDC akọkọ iru rẹ. O sin Ipinlẹ Ondo gẹgẹ bi Alaga ajọ to n bojuto awọn agbegbe ti epo rọbi sodo si nipinlẹ Ondo OSOPADEC.

O dije sipo Gomina nipinlẹ Ondo lọdun 2012 ati 2016.

Isaac Kekemeke

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

A bi Ogbeni Isaac Kekemeke ni ọjọ keji oṣu kejila ọdun 1963 n’ilu Agadagba-Obon nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo nipinlẹ Ondo.

Kekemeke lọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ laarin 1967 si 1975 ni ọpọlọpọ ile ẹkọ nipinlẹ Ogun ati Ondo nitoripe baba rẹ jẹ olukọ. O lọ ileewe girama ni Stella Maris College Okitipupa nipinlẹ Ondo laarin ọdun 1976 ati 1981.

Isaac Kekemeke gba iwe ẹri imọ ofin ni fasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife ti o si da Amofin lọdun 1989. O gba iwe ẹri Masters rẹ nipa imọ ofin ni fasiti Obafemi Awolowo lọdun 2006 ati PHD rẹ ni fasiti Ipinlẹ Ekiti n’ilu Ado.

Kekemeke ti ṣe Amofin fun ọgbọn Ọdun, O ti sin nile igbimọ asofin Ipinlẹ Ondo gẹgẹ bi olori ọmọ ẹgbẹ ti o kere julọ laarin ọdun 1992 si ọdun 1993. O se idasile àjọ NECO gẹgẹ bi alaga akọkọ fún un àjọ naa laarin 2001 si 2004. Bẹẹni o ti ṣisẹ gẹgẹ bi Komisona ati agbefọba agba nipinlẹ Ondo laarin 2003 si 2005, Komisona fun ọrọ isẹ, Ilẹ,Ileegbe ati irinke-rindo ọkọ laarin 2005 si 2007. Akọwe ijọba Ipinlẹ Ondo laarin 2007 si 2009. O si tun jẹ akowe akọkọ fun ẹgbẹ Oṣelu PDP ati alaga akọkọ fẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ondo.

Ni bayi, Kekemeke jẹ Igbakeji alaga ẹgbẹ Oṣelu APC ni Iwoorun-Gusu orileede yi.

Olugbenga Edema

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Olugbenga Edema bẹrẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni L.A Primary School n’ilu Ogogoro nijọba Ibilẹ Ilajẹ nipinlẹ Ondo laarin Ọdun 1972 si 1976 ti o si pari rẹ ni Urban Community School, Abakaliki nipinlẹ Ebonyi lọdun 1977.

O bẹrẹ ile ẹkọ Girama rẹ ni Erinje Grammar School, Ode-Erinje laarin 1977 si 1978 ti o si pari iwe mẹwa rẹ ni Doherty Memorial Grammar School, Ijero-Ekiti, laarin 1978-1982.

Edema lọ fasiti Ilu Ibadan nibiti o ti gba iwe ẹri A/level. O tesiwaju lọ fasiti Obafemi Awolowo Ile-Ife nibiti o ti gba BSc ninu imọ Geography.

Ogbeni Edema tun kawe gboye gẹgẹ bi Amofin.

Gbenga Edema wa nile igbimọ asofin Ipinlẹ Ondo laarin Ọdun 2011-2015. Alaga ajọ OSOPADEC lọdun 2017-2021. O n lo n soju Ipinlẹ Ondo lajọ Niger Delta laarin oṣu kini 2023 si oṣu kejì 2023.

Jimoh Ibrahim

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

A bi Senator Jimoh Ibrahim lọjọ kẹrin-le-lọgbọn oṣu keji ọdun 1967.

Ogbeni Ibrahim jẹ Amofin, Onisowo ati Oloselu, o ti ṣe ọpọlọpọ aseyọri lẹnu isẹ ti o yan laayo. O jẹ alaga ile ẹkọ Global Fleet Group ti ileeṣẹ naa si tan ka awọn ilẹ adulawọ.

Jimoh Ibrahim lọ fasiti Obafemi Awolowo Ile-Ife nibiti o ti kẹkọ gboye nipa imọ ofin tio si ṣe Master rẹ bakanna ni ileewe naa. Lẹyin eyi ni o lọ fasiti Harvard ni Cambridge ni Orileede USS ti O si ni iwe ẹri lọpọlọpọ ẹka.

Ni ọdun 2003 Jimoh Ibrahim dije sipo Gomina labẹ ẹgbẹ Oṣelu ANPP. Ni bayi O n lo n soju ẹkun idibo gusu Ipinlẹ Ondo nile igbimọ asofin àgbà.

Funmilayo Waheed-Adekojo

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Funmilayo Waheed-Adekojo ẹni ti o jẹ obinrin kan ṣoṣo laarin awọn to n dije ni a bi ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu karun 1983.

O lọ Fasiti Ladoke Akintola nibiti O ti kẹkọ gboye nipa imọ Mechanical Engineering ati Masters rẹ nipa imọ Business Administration.

O jẹ gbajugbaja onisowo, ẹni tí to n ran awọn ara ilu lọwọ, ati eni to ni awọn ile-ise pupọ.

Waheed-Adekojo ti seleri lati fowosopo pẹlu awọn obinrin ati lati ṣe moriya fun pelu awọn eto atayese fawọn obinrin ati awọn ọdọ.

Akinfolarin Samuel

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

A bi Ogbeni Akinfolarin Samuel lọjọ karun osu kini ọdun 1962.

Akinfolarin jẹ ọmọ bibi ilu Odigbo nipinlẹ Ondo nibiti o ti lọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Our Saviour Primary School laarin 1969 sì 1974 ati ẹkọ girama rẹ ni Isero Grammar School laarin 1976 si 1981. O tesiwaju lọ College of Advanced Studies Zaria laarin 1985 si 1987. Akinfolarin gba iwe ẹri BSc rẹ ni fasiti Ahmadu Bello lọdun 1990.

Ni ọdun 2003 wọn dibo yan Akinfolarin sile igbimọ asofin Ipinlẹ Ondo labẹ ẹgbẹ Oṣelu PDP tí o si wa nibẹ titi di 2011 ti o si jẹ igbakeji abenugan nigba naa.

Ni 2015 Akinfolarin jawe olubori ninu eto idibo sile igbimọ asoju sofin, ti o si soju ijọba ibilẹ Ile-Oluji/Oke-Igbo/Odigbo labẹ PDP, lẹyin naa o darapọ mọ ẹgbẹ Oṣelu APC lọdun 2017. O tun du ipo naa leekeji ti o si wọle.

Adewale Akinterinwa

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Adewale Olumuyiwa Akinterinwa jẹ ọmọ bibi Ile-Oluji ti a si bi lọjọ kejila Osu Kejila ọdun 1962. O bẹrẹ ile ẹkọ rẹ ni k. kò tún Memorial Nursery and Primary School Surulere nipinlẹ Eko nibẹ lo ti tẹsiwaju lọ Government College Ibadan lọdun 1974. Nibẹ lo ti tẹsiwaju lọ fasiti Obafemi Awolowo nibiti O ti gba iwe ẹri BSc niba Accountancy lọdun 1986.

Gẹgẹ bi akọsẹmọsẹ ó bẹrẹ isẹ ni Banki United Bank for Africa nibiti o ti ṣe agunbaniro NYSC rẹ,bẹẹni O ṣíṣẹ pẹlu Afro Continental Nigeria Limited.

Ni 2009 Dr Olusegun Mimiko yan Akinterinwa gẹgẹ bi Komisona feto owo ina nipinlẹ Ondo. Gomina Oluwarotimi Akeredolu tun yan sipo naa lọdun 2017, eyi tio dimu titi di ọdun 2023 kete lẹyin ipopoda Akeredolu

Ohunyeye Felix

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Olamide Ohunyeye Felix ni a bi lọjọ kẹrin-din-logun osu kokanla 1966 ni Ilutitun Nijọba Ibilẹ Okitipupa nipinlẹ Ondo.

O jẹ ajagun fẹyinti, ti o fẹyinti gẹgẹ bi Brigadier General. Ohunyeye Felix sin Orileede yi lati 1992-2003.

Ajagun fẹyinti naa seleri lati samulo awọn ohun alumoni Ipinlẹ Ondo daradara fun ilo gbogbo eniyan ati fun idagbasoke ilu. O seleri pe ti wọn ba fun laaye lati di Gomina yi o gbe Ipinlẹ Ondo de oke tente bi ti awọn akegbe rẹ.

O seleri lati gbajumọ eto ẹkọ dara dara ati lati mu agbega ba awọn ọdọ, ti o fimo agbekalẹ awọn ile iwosan igbalode si gbogbo ijọba ibilẹ.

Morayo Lebi

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

A bi Ogbeni Morayo Lebi nibi Aadọta ọdun sẹyin n’ilu Akotogbo nijọba ibilẹ Irele.

Lebi jade iwe mẹwa ni ileewe Igbobi College, Yaba nipinlẹ Ondo. O tẹsiwaju lọ fasiti Ipinlẹ Eko nibiti O ti kẹkọ gboye gẹgẹ bi Amofin. O jẹ Amofin ti o gbajugbaja ti o si loruko lawujọ.

O darapọ mọ Oṣelu lọdun 2014.

Dayo Faduyile

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Dayo Faduyile jẹ ọmọ bibi ilu Ikoya nijọba ibilẹ Okitipupa nipinlẹ Ondo sugbọn O fi ilu Eko ṣe ibugbe to si n ṣíṣẹ gẹgẹ bi Dokita to si tun jẹ ọjọgbọn leka eto ilera.

O lọ ile ẹkọ St John’s Primary School, Okitipupa laarin 1976 si 1982. O pari iwe mẹwa rẹ ni Christ School,Ado-Ekiti lọdun 1988.

He had his primary education at St. John’s School, Okitipupa, Ondo State between 1976 and 1982. O kẹkọ gboye MBBS ni fasiti Ilu Eko lọdun 1996. Bẹẹni O tesiwaju lati gba ọpọlọpọ iwe ẹri leka imọ isegun oyinbo titi O fi di Ọjọgbọn leka naa.

Dayo Faduyile dari ẹgbẹ awọn onisegun oyinbo NMA gẹgẹ bi Aare wọn lorileede yi, bẹẹni O Gomina Akeredolu yan sipo gẹgẹ bi Olugbaniniyanu agba lori eto ilera.

Ọwọ́ ọlọ́pàá Ondo tẹ àwọn tó ń tẹ káàdì ayédèrú fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣáájú ètò ìdìbò abẹ́lé APC

Aworan

Oríṣun àwòrán, @Others

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi panpẹ ofin mu afurasi meji ti wọn lọwọ ninu titẹ kaadi idanimọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu iyẹwu wọn ṣaaju eto idibo abẹlẹ ọjọ ẹgbẹ naa ti yoo waye niluu Akure lọjọ Satide.

Eyi waye lẹyin ti ọọfisi ẹgbẹ naa niluu Abuja kede pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ to ba ni kaadi idanimọ ni yoo kopa ninu eto idibo abẹle naa.

Alukoro ileese ọlọọpa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya ninu atejade kede pe ni kete ti wọn sin awọn ni ibẹrẹ ipakọ ni wọn bọ soju iṣẹ ti ọwọ si tẹ awakọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Ariyo niluu Ondo.

Alukoro naa sọ pe awọn ọlọpaa ya bo ile ogbẹni Ariyo, nibi to ti n ṣe iforukọsile fun awọn ọmọ ẹgbẹ APC ki wọn le ni kaadi idanimọ ayederu ṣaaju ọjọ Satide.

O sọ siwaju si pe, wọn ba iwe iforukọsile ẹgbẹ oselu APC, orukọ awọn ọm -ẹgbẹ wọọdu keje niluu Ondo, aworan pelebe mẹtalelaadọta, iwe ti orukọ awọn eniyan wa ati nọmba ẹrọ ilewọ awọn eniyan lọwọ afunrasi yii.

Odunlami-Omisanya salaye pe awọn afunrasi meji yii ti n se iranlọwọ fawọn ọlọpa lati ṣawari awọn to ku to n hu iwa ibi yii.

Bẹẹni komisọna ọlọpa ipinle Ondo, Abayomi Oladipo kilọ fawọn oloṣelu lati ba awọn alatilẹyin wọn sọrọ nibi ti ti wọn ti n gbọ, ki wọn ma si ṣe da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

O ni wọn yoo ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ lati ri daju pe wahala kankan ko waye lasiko eto idibo to abẹle naa to n bọ lọna.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

APC

Oríṣun àwòrán, NPF

Awọn oludije ti ko din ni meje; Jimoh Ibrahim, Olusola Oke, Wale Akinterinwa, Diran Iyantan, Dayo Faduyile, Gbenga Edema ati Jimi Odimayo ni wọn ti kọkọ fọwọsowọpọ lati kọwe si ọọfisi ẹgbẹ naa niluu Abuja.

Awọn meje yii sọ pe ọkan lara awọn oludije sipo gomina ti n tẹ ayederu kaadi ọmọ ẹgbẹ fawọn ti ki n se ojulowo ọmọ ẹgbẹ wọn.

Wọn rawọ ẹbẹ si awọn adari ẹgbẹ naa lati gbe igbese to yẹ ṣaaju eto idibo abẹle ẹgbẹ ọhun.

Awọn oludije yi rọ wọn lati fi orukọ awọn ọmọ-ẹgbẹ ti wọn ti fi orukọ silẹ, ti wọn si ni kaadi ẹgbẹ naa lede ni ibamu pẹlu ifohuntẹlu ajọ INEC.