Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò DNA fún Liam ọmọ Mohbad

Aworan Mohbad ati Wunmi

Oríṣun àwòrán, @_C33WHY_/INSTAGRAM

Ile ẹjọ majisreeti ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn ṣe ayẹwo DNA fun Liam ti i ṣe ọmọkunrin oloogbe akọrin, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad.

Ile ẹjọ paṣẹ yii lẹyin ti ẹbi Mohbad sọ fun ile ẹjọ naa pe awọn fẹ mọ bo ya lootọọ ni Mohbad jẹ baba ọmọ naa.

Ṣaaju ni wọn ti bẹ ile ẹjọ wi pe ki o pa a laṣẹ fun Wunmi to jẹ iyawo oloogbe akọrin naa ki o ṣe ayẹwo DNA fun Liam ni laabu to f’ẹsẹ mulẹ niluu Eko.

Bo tilẹ jẹ pe, pabo ni gbogbo akitiyan ile ẹjọ lati fun Wunmi ni iwe aṣẹ lori igbesẹ naa jasi, ile ẹjọ ti wa pa a laṣẹ bayii pe ayẹwo ọhun gbọdọ di ṣíṣe.

Koda, ile ẹjọ gbiyanju lati wa Wunmi lọ ibi to sọ pe oun n gbe gẹgẹ bi adirẹsi ti o fi sílẹ lati jẹ ki o mọ ibi ti ọrọ de nile ẹjọ.

Ọkan lara ẹbi Aloba, Monisola Odumosu, sọ pe o ṣe pataki ki Wunmi mọ nipa aṣẹ ti ile ẹjọ pa lori ọrọ naa.

Lẹyin ti adajọ majisreeti pàṣẹ pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo DNA fun Liam ni o fikun ọrọ rẹ pe ki wọn wa Wunmi ri lati sọ aṣẹ ile ẹjọ fun un.

Ṣaaju ni Wunmi funra rẹ sọ ninu fidio kan to lu ayelujara pa pe oun ṣetan lati ṣe ayẹwo DNA fun ọmọ oun.

Ẹwẹ, agbẹjọro Wunmi, Ọgbẹni Taiwo Olawale ti sọ pe awọn o mọ nkankan nipa aṣẹ ile ẹjọ lori ọrọ DNA fun Liam.

Amọ, o ni Wunmi ko ni kọ eti ikun si aṣẹ ile ẹjọ ti iwe aṣẹ adajọ majisreeti naa ba tẹ ẹ lọwọ.

Iku Mohbad to waye loṣu Kẹsan an ọdun 2023 ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi.

Eyi ni oriṣiiriṣii iwadii ti fi n waye lori ohun to ṣekupa ọdọmọde akọrin naa.

Koda, ajọ ọlọpaa hu oku rẹ gan an fun ayẹwo lati le mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, igbimọ oluwadii ti ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko gbe dide lori ọrọ naa mu awọn eeyan kan to fi mọ Naira Marley, Primeboy ati Sam Larry lori iwadii ọhun.

Amọ, titi di akoko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ko tii sọ pato ohun to ṣekupa Mohbad.