Ilé aṣòfin Togo buwọ́lu òfin tí yóò mú kí Ààrẹ wà lórí oyè fún ọdún 26

President Faure Gnassingbé

Oríṣun àwòrán, getty images

Ile igbimọ aṣofin Togo ti buwọlu ofin tuntun to ṣe afikun iye saa ti Aarẹ yoo maa lo lori oye bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan sọ pe ofin naa fara jọ iditẹgbajọba.

Eyii n tumọ si pe orilẹede ọhun yoo kuro eto iṣejọba ‘presidential system’ si eto iṣẹjọba ‘parliamentary system.’

Awọn alatilẹyin Aarẹ Faure Gnassingbé sọ pe ofin naa yoo din agbara Aarẹ ọhun ku nitori yoo kan wa lori oye gẹgẹ bii fidihẹ lasan ni.

Amọ awọn alatako ijọba rẹ ni ofun naa yoo fun lanfani lati wa lori alefa fun igba pipẹ.

Pẹlu ofin yii, Faure Gnassingbé yoo wa lori alefa titi di ọdun 2031.

Ọdun 2005 ni Gnassingbé gori alefa lẹyin iku baba rẹ ti oun naa ti wa lori alefa lati ọdun 1967.

Apapọ iye ọdun ti mọlẹbi Gnassingbé ti fi tukọ ijọba orilẹede Togo jẹ ọdun mẹtadinlọgọta.

Oṣu to kọja ni awọn aṣofin buwọlu ofin tuntun naa amọ Aarẹ Gnassingbé dawọ imulo rẹ duro fun igba diẹ lẹyin ti ọpọ araalu tako o, eyii to mu ko sọ pe awọn yoo tun ṣagbeyẹwo rẹ siwaju si.

Minisita fun ẹtọ ọmọniyan, Yawa Djigbodi Tségan sọ pe igbesẹ naa yoo tubọ fun eto oṣelu ijọba awarawa lagabra si nilẹ ọhun.

Ṣugbọn oludije sipo Aarẹ lakoko kan, Brigitte Kafui Johnson, to jẹ olori ẹgbẹ alatako CDPA ti juwo ofin tuntun naa gẹgẹ bii igba ti Aarẹ ba n fi tipatipa ja agbara gba lọwọ araalu.