Ọjọ́ 25 lẹ́yìn tí mo pàdé ọ̀rẹ́kùnrin mi ni mo di àfẹ́sọ́nà rẹ̀ – DJ Cuppy  

DJ Cuppy

Oríṣun àwòrán, cuppymusic

Ifeoluwa Florence Otedola, ọmọ baba olowo, Femi Otedola ti ọpọ mọ si DJ Cuppy ti sọ pe ọjọ marundinlọgbọn sẹyin ni oun pade afẹsọna oun.

DJ Cupppy lo fi ọrọ naa lede lawọn opo oju ikansiraẹni rẹ lori ayelujara lalẹ ọjọ Aje.

Lati igba ti Cuppy ati afẹsọna rẹ ọhun ti n fẹ ara wọn ni wọn ko ti jẹ ki awọn ololufẹ rẹ lori ayelujara gbadun mọ pẹlu oniruru awọn aworan ti wọn maa n fi sita.

Lasiko to n sọrọ nipa bo ṣe di iyawo afẹsọna loju opo Twitter rẹ, o ni “mo le sọ ni gbangba bayii pe mo ti di iyawo afẹsọna.”

O ni ibi idije ọkọ wiwa kan niluu Abu Dhabi loun ati ọkunrin naa ti pade ara wọn.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko tii to oṣu kan ti awọn mejeji pade ara wọn ti ọkunrin naa sọ pe yoo wu oun lati fi oun (Cuppy) ṣaya, oun si gba bẹẹ.

O ni “nibi idije ọkọ wiwa @Gumball3000 ni mo ti pade ifẹ aye mi.”

Atẹjade ti Cuppy fi lede kẹyin yii waye lẹyin ti awọn eeyan kan fi fidio kan lede lati ṣafihan pe oju afẹsọna rẹ naa ko gbe ‘bikan ti fidio ọhun si tan ka ori ayelujara.

Ta ni Ryan Tailor, afẹsọna DJ Cuppy?

Abẹṣẹkubiojo ọmọ ilẹ Gẹẹsi ni Rayan Tailor, o si di gbajumọ nipa awọn fidio rẹ to maa n fi lede loju opo YouTube rẹ.

Iye eeyan to n tẹle Ryan loju opo YouTube rẹ ọhun din diẹ ni miliọnu meji abọ, eyii to ṣi ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2011.

Wọn fofin de Ryan ninu ọsu Kẹta ọdun yii lẹyin to fi ori gba DK Money ti wọn jọ n ja.

Gẹgẹ bii ohun to sọ loju opo Instagram rẹ, Ryan Talior ti bi ọmọ ọkunrin kan.

Ta ni DJ Cuppy?

DJ Cuppy ni ọmọ baba olowo ọmọ Naijiria Femi Otedola, amọ bo tilẹ jẹ pe baba rẹ lọrọ pupọ, o ṣiṣẹ funra rẹ titi to fi lorukọ lawujọ.

Cuppy jẹ olorin, DJ, akẹkọọ ati ẹlẹyinju aanu.

Ẹnu lọọlọ yii lo ṣẹṣẹ kẹkọọ gboye ni Fasiti Oxford, nilẹ Gẹẹsi.

Lara awọn orin rẹ to gbajumọ ni “Gelato” ti oun ati Zlatan gbe jade.