“Mo fẹ́ mọ̀ bóyá nǹkan ọkùnrin mi ń ṣiṣẹ́ dáadáa ni mo ṣe bá ọmọ ọdún mẹ́ta lòpọ̀”

Ọlọpaa ati afurasi

Oríṣun àwòrán, Nigeria Tribune

Ọwọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, ti ba ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Farouk, to fi ipa ba ọmọ ọdun mẹta lopọ.

Agbegbe Popo Yemoja nilu Ibadan, ni isẹlẹ naa ti waye ni alẹ Ọjọbọ to kọja.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Nigerian Tribune ti salaye, Ikọ Amọtẹkun lo gba ọkunrin naa mu nigba ti iroyin nipa iwa ibi to hu ọhun de etigbọ wọn.

Lẹyin naa ni wọn fa le ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lọwọ.

Bawo ni isẹlẹ naa se waye?

Gẹgẹ bi iroyin naa se wi, ọmọ ọdun mẹta naa sun si ẹgbẹ iya rẹ agba lori ẹni ni faranda ile wọn lalẹ ọjọ ti isẹlẹ naa waye ni. ti wọn si n gba atẹgun sara nitori ooru amuju to n mu, ki wọn to wọle lọ sun.

Farouk yii si lo wa lati gbe ọmọdebinrin naa wọ inu yara rẹ nibi to ti n gbe yara kan pẹlu ẹlomiran.

Inu yara naa si lo ti gbe ọmọde naa le nnkan ọkunrin rẹ, o n wọle. Jade, titi to fi da omi ara nnkan ọkunrin si ọmọde naa lara.

Bi o tilẹ jẹ pe ọmọdebinrin naa n ke, to si n jẹ irora amọ Farouk ko gbọ, titi to fi tu ara rẹ lara, to si gbe ọmọ naa silẹ pada ni ori ẹni lẹgbẹ iya rẹ agba.

Ni kete to de ori ẹni naa, ni ọmọ ọhun sun lọ sugbọn nigba ti baba ọmọ naa wa gbe lori ẹni lo se akiyesi pe oje to ki ti lẹ mọ ọmọ naa lara ni itan ati idi.

Ẹnu ya ọkunrin naa, to si gboorun oje ara ọmọ rẹ, nibẹ si lo ti sawari rẹ pe oje nnkan ọkunrin ni wọn da si ara ọmọ ọdun mẹta naa lara.

“Ọmọ ọdun mẹta naa, tii se ọmọ kẹta fun idile naa, padanu iya rẹ lẹyin to bi ọmọ kẹrin losu kẹjọ ọdun 2023 to kọja”

Ọmọ ọdun mẹta naa, tii se ọmọ kẹta fun idile naa, si lo ti padanu iya rẹ ni ọjọ karun lẹyin to bi ọmọ kẹrin losu kẹjọ ọdun 2023 to kọja.

Idi si ree ti iya agba naa fi wa lati Eko wa tọju awọn ọmọ mẹrẹẹrin ti oloogbe fi silẹ saye lọ.

Nigba to n salaye ọrọ naa, Baba ọmọdebinrin naa ni “Mo lọ tọju awọn adiẹ ti mo n sin ni, ti mo si tẹ ọmọde naa si ẹgbẹ iya agba, lẹyin eyi ni mo lọ tun ki awọn ọrẹ mi ladugbo nigba ti oorun ko kun mi.

Bi mo se kẹẹfin isẹlẹ naa, mo lọ sọdọ ikọ amọtẹkun , ti wọn si wa ko gbogbo awọn ọkunrin to wa ninu ile wa lati mọ ẹni to sisẹ ibi yii.

“Lati bii ọdun mẹwa ni nnkan ọkunrin mi ko ti sisẹ, idi si ree ti n ko fi ni ọrẹbinrin kankan rara”

Asiko ti wọn n fi ọrọ wa awọn ọkunrin naa lẹnu wo ni Farouk jẹwọ pe oun ni oun sisẹ ibi naa, ti wọn si fa le agọ ọlọpaa to wa ni Mapo lọwọ.

Lootọ ni ko mọọmọ jẹwọ ẹsẹ naa, amọ se ni ọmọ mi n naka si pe oun lo gbe oun, amọ to n yari pe oun ko mọ ohun kohun nipa isẹlẹ naa.”

Ninu alaye rẹ lẹyin to jẹwọ tan, Farouk ni oun ba ọmọde naa lopọ tori oun fẹ se ayẹwo nnkan ọkunrin oun boya o si n sisẹ daada ni nitori o ti pẹ ti oun ti ba obinrin lopọ.

Afurasi naa, to ni oun n kọ isẹ awọn to n ta eroja ohun elo alo ina ni “Ọrọ naa ko tiẹ ye mi pẹlu.

Lati bii ọdun mẹwa ni nnkan ọkunrin mi ko ti sisẹ, idi si ree ti n ko fi ni ọrẹbinrin kankan rara.

Se ni ọmọ naa n pariwo gidi, mo si fi silẹ amọ mo da oje nnkan ọkunrin mi si lara, lẹyin naa ni wn wa mu mi lọjọ Ẹti.”

Wọn ti gba gbe ọmọ naa lọ sile iwosan, ti wọn si ri oju apa pe lootọ ni nnkan to wuwo lọ oju itan rẹ amọ ko ja ibale rẹ rara.