Obìnrin tí wọ́n jí gbé tọmọ tọmọ àmọ́ tí ẹkún ọmọ da àwọn ajínigbé láàmú bá BBC sọ̀rọ̀

“Mo ti kọ́kọ́ ni mi ò wọ Marúwá, bó ṣe ní àní mo ní kóo wọlé sẹ́ẹ̀, nǹkan tí mo mọ̀ mọ kò jù ìyẹn lọ́.”

Jẹjẹ ni Rukayat n lọ si ibi iṣẹ rẹ ni ọjọ kan ninu oṣu kini ọdun yii ni agbegbe Igando, ipinlẹ Eko to ṣe kongẹ agbako lọwọ awọn ajini-ji-ọmọ gbe.

O ṣalaye fun BBC Yoruba pe kete ti oun bọlẹ ni ọkada ti oun gun pẹlu ọmọ lẹyin ni awakẹkẹ Maruwa kan ke si oun pe ki oun wọle.

Mo ti kọ́kọ́ ni mi ò wọ Marúwá, bó ṣe ní àní mo ní kóo wọlé sẹ́ẹ̀, nǹkan tí mo mọ̀ mọ kò jù ìyẹn lọ́.

Rukayat Sodiq

O ṣalaye bi oun atawọn meji ti wọn wọ Kẹ̀kẹ́ Márúwa naa ṣe n tẹle gbobo ọrọ ti ẹni to wa a n pa laṣẹ fun wọn.

“Igba ti wọn ni kaa wọ bọọsi, awa mẹtẹta wọ ọ, wọn gba gbogbo foonu wa, baagi wa ati gbogbo nnkan.

Rukayat ṣalaye pe awọn ba awọn eeyan ninu bọọsi ọhun amọ gbogbo wọn ko le sọrọ.

“Gbogbo awọn ọmọ to wa ninu bọọsi ọhun ti sùn, awọn agbalagba to wa nibẹ naa kan n wo ni, wọn o sọ nnkakan”.

“Baa ṣe wọ inú mọ́tò yẹn báyìí, ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní sun ẹkún gidi.

Mo ṣáà nń gbọ́ ohùn ọmọ mi àmọ́ mi ò lè ṣe nǹkankan

Ile Rukayat

Rukayat ṣalaye pe igba ti oun rii pe ariwo ọmọ oun n pọ sii loun sọ pe ki wọn ba oun gbe ọmọ oun.

O sọ fún ọmọ mi (ìkókó) tó ń ké pé “tóò bá dákẹ́, kò ná mi ní nǹkankan láti ṣá ẹ ní àdá wẹ́lẹwẹ̀lẹ”.

“Wọ́n ní àmì burúkú wà lára ọmọ yìí, bi wọn ṣe ni ki n bọ silẹ niyẹn lati maa lọ”.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí