Godwin Emefiele, gómìnà báńkì CBN ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọ̀gá báńkì, wo ohun tó sọ lórí owó tuntun

Godwin Emefiele, gomina banki apapọ NAijiria CBN, ati aworan owo naira tuntun

Gomina Banki apapọ orilẹede Naijiria, Godwin Emefiele ni oun ti ṣe ipade pẹlwaọn ọga agba banki marundinlogun lorilẹede Naijiria, ti oun si ti paṣẹ fun wọn pe ki wọn rii daju pe owo igba naira wa larọwọto araalu bẹrẹ lati Ọjọbọ.

Godwin Emefiele sọ eyi ni Ọjọbọ lẹyin to ṣe ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbimọ alabẹṣekele ti ile aṣojuṣofin gbe kalẹ lori ọrọ ayipada naira.

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ ni ile aarẹ nilu Abuja, Emefiele to ṣe apejuwe ara rẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ sin awọn ọmọ Naijiria rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn gba eto naa laye lati ṣiṣẹ nitori pe oun nigbagbọ pe yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje Naijiria nipa didẹkun ipenija kiko owo jọ lọna ti ko ba ofin mu.

O ni suuru to lọjọ ni ipenija ti ilana ayipada owo naa n mu ba araalu bayii, inu oun ko si dun iṣoro rẹ. Amọṣa o ni banki apapọ CBN yoo tubọ maa sa ipa rẹ lati din inira yii ku.

Ṣaaju lowurọ Ọjọbọ ni aarẹ Buhari ti dari banki apapọ CBN pe ko ko awọn owo naira igba naira sigboro pẹlu awọn owo tuntun igba, ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun kan naira fun ọgọta ọjọ.

Amọṣa, aarẹ ni opin ti de ba okun ẹmi ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun kan niara to wa fun nina tẹlẹ.

Bakan naa ni Aarẹ Buhari tun tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori inira ti wọn n ba finra nitori ayipada owo naira tuntun naa.