Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Sango, ìpínlẹ̀ Ogun àti Mile 12, Ikorodu, Oke koto Agege

Ifẹhonuhan ni Naijiria

Ija igboro ati ifẹhonuhan tun ti bẹ silẹ lawọn apa ibi kọọkan ni ipinlẹ Eko ati ipinlẹ Ogun.

Eyi n waye latari ọwọngogo owo Naira to gbode kan jakejadeo Naijria.

Lowurọ oni ni awọn akọroyin ko iroyin jọ pe awọn araalu ti da igboro ru ni awọn agbegbe bii Mile 12, Ketu, Ojota, Okekoto Agege ni Eko.

Iroyin to tẹ wa lọwọ naa sọ pe ṣe lawọn eeyan tu si igboro ti wọn si n ṣe ikọlu si awọn to n wa ọkọ to bẹẹ ti awọn awakọ n sọ fun ara wọn pe ki wọn pa ọna wọn da si ibomiran.

Rogbodiyan Naijiria

Iroyin tilẹ ni awọn eeyan n gbọ iro ibọn lawọn agbegbe kan ṣugbọn a ko tii le fi aridaju rẹ han.

Ki ni Ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ?

Ẹwẹ, alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekom Benjamin hundeyin ti fi aridaju ti iṣẹlẹ agbegbe Mile 12 amọ awọn ti ran awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati boju to abo ibẹ.

Hundeyin fi eyi lede loju opo Twitter rẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n ta orukọ rẹ mọ awọn fọnran ati aworan ti wọ́n n pin sori ayelujara.

O fesi pe “lootọ ni. Awọn Eeyan wa wa nibẹ. A ti ran ikọ alabojuto abo lọ sibẹ. Ẹ rii pe ẹ wa ni ipo abo gẹgẹ bi a ṣe n bojuto taa si n mu adinku ba iṣẹlẹ naa.”