Ó ṣe! Ọmọ olóògbé Soun Ogbomosho náà tún dágbére fáyé

Ọjọgbọn Taibat Danmole

Oríṣun àwòrán, Others

Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole, tó jẹ́ àkọ́bí lóbìnrin fún olóògbé Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Oyewumi Ajagungbade ti dágbére fáyé.

Àdánu yìí wáyé ní bí ó ṣe kù sáátà kí ó pé oṣù kan tí bàbá rẹ̀ re ìwàlẹ̀ àṣà.

Nigba ti BBC Yoruba kan si Aafin Soun, oṣiṣẹ kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ jẹ ko di mimọ pe lootọ lo ṣẹlẹ.

Ọdún mọ́kànléláàdọ́rin ni Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole lò lókè èèpẹ̀ kó tó jẹ́ Ọlọ́run ní pè.

Ṣaaju ki Oba ilu Ogbomosho yii ku naa lo ti kọkọ padanu ọmọ rẹ ọkunrin kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lábẹ́ ìjọba ológun kú sí ìlú Ìlọrin lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.

Iroyin ni, olukọni ni Arabinrin Taibat jẹ ni ile ẹkọ giga Fasiti ti ilu Ilorin.

Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole ni wọ́n ti sin ní ìlànà Mùsùlùmí.