Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi àwòrán Raheem Adedoyin léde láwọn ìwé ìròyìn lórí ikú Timothy Adegoke

Raheem Adedoyin

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ majisireeti kan niluu Abuja ti paṣẹ pe ki wọn fi orukọ ati aworan Raheem Adedoyin, to jẹ ọmọ Rahman Adedoyin to ni ile itura Hilton ni Ile Ife lede.

Aṣẹ yii waye lẹyin ti ile ẹjọ naa kede pe Raheem Adedoyin lọwọ ninu iku Timothy Adegoge to ku sile itura naa lọdun 2021.

Aṣẹ ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat

Aṣẹ ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat

Adajọ Elizabeth Jonnes Wonni sọ ninu iwe aṣẹ naa pe afurasi ọhun lọwọ ninu iku oloogbe naa, eyii to waye niluu Ile Ife lọjọ karun un, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Iwe naa ni ile ẹjọ ọhun “Paṣẹ pe ki wọn fi orukọ ati aworan afurasi lede pẹlu erongba lati fi ṣikun ofin mu.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lara awọn iwe iroyin ati ati ileeṣẹ iroyin ti ile ẹjọ naa paṣẹ pe ki wọn ti fi orukọ ati aworan Raheem Adedoyin lede ni Punch, Vanguard, Daily Trust, to fi mọ ileeṣẹ iroyin Channels, NTA, TVC, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ile ẹjọ ọhun ni ki wọn kede orukọ ati aworan Raheem Adedoyin ninu awọn iwe iroyin ọhun “Nitori o lọwọ ninu iku Timothy Adegoke to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji, to si fẹsẹ fẹ lẹyin iṣẹlẹ naa.”

Ẹwẹ, egbọn oloogbe naa, Adegoke Olugbade sọ fun akọroyin BBC pe Raheem Adedoyin gan lo ṣe amọna bi wọn ṣe pa aburo oun nile itura baba rẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Raheem Adedoyin ti wọn n wa yii gan lo tẹle awọn to gbe oku aburo Timothy Adegoke jade ninu ile itura naa lasiko ti wọn fẹ lọ ju oku rẹ sinu igbo.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ko awọn akọṣẹmọṣẹ agbofinro sọdi lati bẹrẹ iwadii lori bi ọrọ naa ṣe waye.

Lasiko naa ni wọn fi ṣikun ofin mu oludasilẹ ile itura Hilton, Oloye Rahman Adedoyin pẹlu awọn marun un mii ti ọrọ naa kan.

Lati asiko ti iwadi ọhun ti bẹrẹ ni ọmọ rẹ Raheem Adedoyin ti na papa bora titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, eyii to mu ile ẹjọ kede pe ki wọn fi orukọ ti aworan rẹ lede lọna ati ri mu.