Irọ́ ni pé àwòrán CCTV ṣàfihàn bí Ramon Adedoyin ṣe pa Timothy Adegoke – Agbẹjọ́rò Adedoyin

Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, @NatashaOfLagos

Ọkan lara awọn agbẹjọro to n ṣoju Ramon Adedoyin, to ni ile itura Hilton ti Timothy Adegoke ku si ni Ile Ife ti ni ki awọn eeyan má naani iroyin to n lọ ni igboro pe ẹrọ ayaworan CCTV kan ti tu aṣiri bi wọn ṣe pa oloogbe naa nile itura ọhun.

Agbẹjọro naa, Abiodun Williams sọ pe iroyin ọhun ti akọroyin kan, Oriyomi Hamzat n gbe kiri ko ni ootọ kankan ninu.

Williams sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti Hamzat yoo gbiyanju lati ba orukọ Adedoyin jẹ loju awọn araalu, paapaa lẹyin ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi atẹjade kankan sita nipa ibi ti wọn ba iṣẹ de, ati pe Adedoyin funra rẹ ko si nile itura naa lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, nitori naa, o ṣoro fun lati wa ninu aworan CCTV ti wọn n sọ nipa rẹ.

Agbẹjọro naa ni “A ti gbọ pe ọgbẹni Hamzat ti n sọ oniruru ọrọ kobakungbe lodi si Adedoyin ati mọlẹbi rẹ lati igba ti Timothy Adegoke ti jade laye.”

“A fẹ fi akoko yii sọ fun awọn araalu pe ki wọn ma naani irọ ti okunrin naa n pa fun wọn ṣugbọn ki wọn duro de esi abajade iwaddi awọn ọlọpaa lati mọ bi ọrọ iku oloogbe naa ṣe jẹ.”

“Imọran wa si Hamzat atawọn eeya mii to ba mọ ohunkohun nipa iku Adegoke ni pe ki wọn tọ ileeṣẹ ọlọpaa lọ ki iwadii wọn le ya.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹjọro naa fi kun pe ile ẹjọ nikan lo le kede pe afurasi kankan jẹbi ẹsun ti wọn ba fi kan, nitori naa ki Hamzat atawọn eeyan mii to ba n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri, tabi ti wọn ba n ṣedajọ laye ara wọn lọ sinmi agbaja.

O pari ọrọ rẹ pe kii ṣe ori ayelujara ni o tọ lati maa kede pe afurasi jẹbi ẹsunkẹsun lai gba ile ẹjọ laye lati ṣiṣẹ wọn.

Ṣaaju ni Hamzat, to jẹ akọroyin, ajafẹtọ ati sọrọ-sọrọ ori redio ti kọkọ kede loju opo Facebook rẹ pe ọwọ oun ti tẹ aworan CCTV kan, eyii to ṣafihan bi Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ kan ṣe pa Adegoke nile itura naa lọdun 2021.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ