Nìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín Ààrẹ Buhari buwọ́lu àtúnṣe abádòfin ètò ìdìbò, ó d’òfin

Aarẹ Buhari atawọn aṣofin

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Nibayii, ohun táwọn eeyan n reti lati bii ọjọ mẹta ti di mímúṣẹ gẹgẹ bo ṣe ti buwolu àtúnṣe abadofin eto idibo Naijiria to si ti di ofin bayii.

Ni ọsan ọjọ Ẹti ni Ààrẹ buwolu u nibi eto ránpẹ kan ti wọn ṣe ni ile Ààrẹ ni ilu Abuja.

Adari ile igbimọ aṣofin agba, Ahmed Lawan ati adari ile igbimọ aṣojú-ṣofin, Femi Gbajabiamila naa wa lara awọn ti ibuwolu naa ṣojú wọn.

Eyi waye nigba to ku bíi ọ̀sẹ̀ kan to yẹ ki gbedeke iye ọjọ ti Ààrẹ ni lati ṣe ìpinnu yìí pé gẹ́gẹ́ bi alakale òfin Naijiria.

Nigba to ti tẹ́wọ́ gba abadofin naa latodo ilé igbimọ aṣofin lati ọjọ Kọkànlélọ́gb Oṣù Kini làwọn tọrọ kan kaakiri tí ń fojú sọ́nà de ki adari Naijiria buwolu u.

Ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ yii làwọn eeyan ti kọkọ ri italolobo pé Ààrẹ yóò buwolu u àmọ́, ó kùnà, wọn si tun ọjọ àtiṣe omii dá.

Ọpọlọpọ ìgbà tí ṣíṣe àtúnṣe òfin idibo tí kùnà ni Nàìjíríà

Gbogbo igba ti wọn ti gbiyanju lati ṣe àtúnṣe òfin eto idibo Naijiria lásìkò àwọn ilé igbimọ aṣofin Kẹjọ lábẹ́ akoso Bukola Saraki àti Yakubu Dogara lo foriṣanpọn àmọ́ àwọn asofin ni saa ikẹsan yìí ṣe àṣeyọrí rẹ bo tilẹ̀ jẹ pe awọn náà koju ifaseyin díẹ̀.

Ààrẹ Buhari ti kọkọ kọ láti buwolu nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2021 to sì tọ́ka sí owó tí yóò na orileede láti ṣe idibo abẹle, ipenija aabo àwọn igbesẹ to seese ko da ibo ru táwọn oloselu máa ń gbé gẹgẹ bi ìdí tó ṣe ṣe ìpinnu yẹn o si padà sọ awọn ìdí tó fi buwolu u.

Ní báyìí, ilé igbimọ aṣofin tí ṣe àtúnṣe abadofin náà láti fà ayé gba idibo abẹlee o-ṣoju-mi-koro àti idibo abẹle àlá ṣojú, adéhùn ṣíṣe àti yiyan àwọn oludije ẹgbẹ́ òṣèlú.

Ẹ̀dá abadofin èyí tí ilé igbimọ aṣofin méjèèjì jọ pawopo ṣe ọhun lọ dé ọwọ Ààrẹ Buhari lẹyin ọ̀sẹ̀ kan ti wọn parí rẹ gẹgẹ bi oluranlowo pàtàkì Ààrẹ lórí ọrọ ilẹ̀ asofin, Ṣẹnetọ Babajide Omoworare.