Kíni ìkọlù Russia sí Ukraine ń se lórí búrẹ́dí títà àti rírà ní ilẹ̀ Adúláwọ̀?

Aarẹ Russia ati aarẹ Cyril Ramaphosa South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O le dabi ẹni pe o jina siwa ṣugbọn ogun to n waye ni Ukraine le ko ipa ribiribi lori awọn eeyan orileede Afrika kọọkan.

Ẹ bi mi wipe bawo lo ṣe ri.

Akọk ni nipasẹ ọrọ aje, koda o tun le mu ki awọn olori bẹrẹ si ni kaya soke lori ẹni ti wọn yoo gbe lẹyin laarin Russia ati awọn alagbara aye miran.

Ni Naijiria ni paapa, ọrọ yi bu iso sini lẹnu to tun buyọ si paapa ba baa woye pe ọrọ naa niṣe pẹlu iṣejọba awarawa ati ipinnu awn kan lati ya sọtọ.

Ninu apilẹkọ kan ti akọroyin ileeṣẹ iroyin Daily Maverick ni South Africa kọ, wọn ni ogun to n waye ni Yuroopu yi yoo milẹ titi de awọn abule ati ilu South Afrika ati ibomiran lagbaye.

“Koda ki wọn to yin ado oloro alakọkọ, ogun yi ti lapa: aimọye biliọnu dọla ni wọn ti fi ra nkan ogun,owo to yẹ ki wn fi koju iṣẹ,ajakalẹ arun,eto ẹkọ,aisedeede laarin awọn eeyan ati ipenija iyipada oju ọjọ”

Mark Heywood akọroyin to kọ apilẹkọ yi lo sọ bayi

Aworan Sunday Igboho afihan Yoruba Nation ati aarẹ Russia Vladimir Putin

Bawo ni ikọlu yi yoo se kan wa ni Naijiira

BBC Pidgin ba onimọ meji nipa ọrọ ilẹ okere ati ọrọ aje sọrọ.

Ọgbẹni Bismark Rewane ati Ọjọgbọn Bola Akinterinwa sọ iwoye wọn nipa ogun yi.

Bisamark sọ pe ”gbogbo igba ti nkan ba ṣelẹ lagbaye yoo nipa lori iye owo ọja ni ibomiran.”

O ni bi ikọlu yi ba di ogun to gbale to gbode, ”iye owo epo rọbi yoo lọ soke iye owo ọja yoo wọn si, dọla yoo gberi idarudapo yoo si ṣẹlẹ lẹka karakata lagbeye.”

Amọ o sọ pe Naijiria yoo jẹ anfaani alekun owo sinu akoto wọn nipa owo epo rọbi to ba n lọ soke si.

Ọrọ oṣelu awarawa ati ominira idajọba ṣe lo n waye ni Ukraine

Ọjọgbọn Bola Akinterinwa ni oun gbabọ pe ohun to n waye ni Ukraine kii ṣe ọrọ ogun bi kii ṣe ija ominira ati iyara ẹni sọtọ.

O ni ipe fun ijọba awarawa lo n da wahala silẹ ni Ukraine.

O tẹsiwaju pe Amẹrica ati awọn orileede NATO to n gbe lẹyin Ukraine sọ pe Ukraine lẹtọ lati sọ boya awọn fẹ wa pẹlu Russia tabi ki wọn ya sọtọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ṣafiwe eleyi pẹlu nkan to n waye ni Naijiria bawọn ikọ IPOB ati Yoruba Nation ṣe n pe fun iyasọtọ kuro lorileede Naijiria.

O ni bi Naijiria ba da si ọrọ yi ti wọn gbe lẹyin Ukraine, yoo jẹ ki o dabi ẹni pe wọn ṣetan lati fun awọn ajijagbara bi Yoruba Nation ati IPOB ni nkan ti wọn n beere.

Lagbaye awọn orileede to n gbe lẹyin Ukraine lo pọ. Naijiria ko si ni fẹ ko dabi ẹni pe ti wọn yatọ si ara yoku.

Ọrọ yi wa dabi ẹni pe iwaju ko ṣe lọ, ẹyin naa ko si ṣe pada si.

Kini ohun ti ilẹ Afrika sọ si ogun to wọle de yi?

Naijiria ni tirẹ sọ pe iyalẹnu lo jẹ fawọn pẹlu nkan ti Russia ṣe yi.

Titi di ba ṣe n ko ọrọ yi jọ, ko si orileede Afrika kankan to gbaruku ti Russia.

South Africa nibi ti idagbasoke ọrọ aje ti gbooro julọ lAfrika ti sọ pe ki Russian ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Ukriane ni kiakia ki wọn si fi tubi n nubi yanju ọrọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Atẹjade lati ọdọ ijọba ilẹ naa sọ pe ”Ko si ohun ti Ogun n mu wa bi kii ṣe inira ati ipalara to se pe ni Ukraine nikan kọ ni yoo ti lapa bi kii ṣe kaakiri agbaye.Ko si orileede to mori bọ ninu rẹ”

Ohun ti South Afrika sọ yii dabi pe wọn tafa oro si Russia ni nitori Russia ri wọn gẹgẹ bi alajọṣepọ to mọnranyin ni Afrika.

Awọn mejeeji ni ajọṣepọ nipa jijẹ ọmọ ẹgbẹ awọn orileede to n dagba soke bọ taa mọ si Brics.

O kere tan idokowo South Africa to wa ni Russia fẹ ẹ to 80bn South African rand eyi tii ṣe $5bn; £3.7bn. Idokoowo Russia ni South la gbọ pe o to 23bn rand

Ni tirẹ Kenya naa ti bẹnu atẹ lu ohun ti Russia ṣe.

Martin Kimani to jẹ aṣoju Kenya ni igbimọ aabo ajọ iskan agbaye sọ pe ”Russia ti tasẹ agẹrẹ wọ aala orileede Ukriane.Niṣe ni wn n tẹ oju ofin to de ajọ UN mọlẹ nipa aṣilo agbara awọn to lagbara”

Ghana ati Gabon naa bẹnu atẹ lu Russia.

Koda Mali ati Central African Republic nibi tawọn ọmọ ogun Russia ti n ba wọn koju agbesunmmi, wọn dakẹ sọrọ yi ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni ikọlu yi yoo ṣe kan emi ati iwọ ni Afrika?

Owo epo rọbi re kọja ọgọrun dọla nitori ikọlu yi.Iye yi lo pọ julọ ti wọn ra epo lati ọdun 2014.

O ṣeeṣe ki owo isuna awọn orileede bi Naijiria ati Angola burẹkẹ si nipa owo epo to lọ soke yi amọ iye owo ọkọ yoo lọ soke fọpọ eeyan nil Afrika.

Eleyi yoo nipa lori iye owo ọja miran lọja.

Awọn onimọ kan sọ pe o ṣeese ki owo burẹdi wọn si nitori Russia ati Ukraine lo n pese wheat to pọ julọ lagbaye.

Aworan arakunrin kan to n ta burẹdi ni Egypt

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni awọn orileede to wa ni ariwa Afrika, ọwọngogo tabi alekun owo iye burdi ko ṣẹṣẹ maa da wahala silẹ.

Arab Spring to waye gẹgẹ bi arakunrin Smith ti ṣe sọ, Egypt, Tunisia, Libya ati Algeria to ṣe pe wọn ko le ṣalai lo wheat wa ninu ewu nla nitori ikọlu yi.

Kenya naa to ṣe pe Russia maa n ra tea lọwọ wọn wa ninu ewu pipadanu owo lati ilẹ okere ti Russia ko ba bawọn ra tea wọn.

Obinrin kan n ṣiṣe ninu oko tea lorileede Kenya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn akẹkọọ to wa ni Ukraine naa n ke irora

Ọjọ ti pẹ tawọn akẹkọọ Afrika ti n salọ si Ukraine lọ kawe nitori pe owo ile ẹkọ wọn ko gbowo lori pupọ.

Ni ẹka imọ iṣegun oyinbo ni paapa, Ukraine jẹ ogunagbongo ibi tawọn eeyan ti n kẹkọọ imọ iṣegun.

Bi ogun ti ṣe bẹ silẹ bayi, awọn akẹkọọ Afrika lati Naijiria, Ghana ati ibomiran ti n ke gbajare si ijọba wọn lati pese aabo to peye fun wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ijọba Naijiria lawọn ti n ṣeto lati gbe ẹnikẹni to ba fẹ pada wa sile ni kete ti wọn ba ṣi papakọ ofurufu ilẹ Ukraine.

Bi nkan ti ṣe ri bayi, o ṣeesẹ ki eto ẹkọ awọn akẹkọọ yi fori ṣanpọn ti wọn yoo si ni lati pada sile titi di igba ti alaafia ba pada si Ukraine.

Awọn orileede Afrika ti wọn lakẹẹkọ to pọju lọ niUkraine ni Morocco (8,000), Nigeria (4,000) ati Egypt (3,500).