NÍ YÀJÓYÀJÓ Ìbọn ń ró kù kù gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ọ̀pọ̀ aráàlù ṣe tẹ ìbọn ní Kyiv láti dojú kọ Russia

Ààrẹ
Liberia, George Weah, ti bojú àánú wo Mínísítà fètò ààbò àná ní orílẹ̀ èdè náà,
Brownie Samukai, ẹni tí ilé ẹjọ́ dá ẹ̀wọ̀n fún fẹ́sùn pé ó kó owó jẹ.

Pẹ̀lú
ojú àánú yìí, ó túmọ̀ sí pé ó le padà sí ilé ipò Sẹ́nétọ̀ láti máa ṣiṣẹ́ kó le
máa rí owó dá padà fún ìjọba, tí kò sì ní wọ lwọ̀n rárá.

Samukai
àti àwọn ènìyàn méjì mìíràn tó ṣiṣẹ lábẹ́ rẹ̀ ni ilé ẹjọ́ dá ẹ̀wọ̀n fún fẹ́sùn
wí pé wọn kò le ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ná owó tó lé ní mílíọ̀nù dọ́là tó jẹ́ owó tí
wọ́n ń yọ nínú owó oṣù àwọn ọmọ ogun.

Nígbà
tí Samukai wà ní Mínísítà lábẹ́ ìjọba Ààrẹ Ellen Johnson Sirleaf ni wọ́n ń yọ
owó náà láti bá àwọn ọmọ ogun náà fi pamọ́.

Samukai
lásìkò ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ní àwọn iṣẹ́ ìlú ni àwọn fi owó náà ṣe pẹ̀lú àṣẹ Ààrẹ
Sirleaf.

Mínísítà
kan lábẹ́ Weah ní ìjọba yóò dá àwọn ọmọ ogun náà padà tí Samukai, yóò sì máa dá
owó padà fún ìjọba ní tirẹ̀.


ọdún 2020 ni wọ́n dìbò yan Samukai ní gẹ́gẹ́ bí sẹ́nétọ̀ ní ẹkùn Lofa County.

Ṣaájú
ni ilé ẹjọ́ ti dá ẹjọ́ pé kí Samukai wà ní ẹ̀wọ̀n títí yóò fi san owó náà padà
tán.

Copyright: Getty Images