NÍ YÀJÓYÀJÓ Peter Mbah la Labour Party mọ́lẹ̀ ní Enugu gẹ́gẹ́ bí gómìnà tuntun

Copyright: OTHERS

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti
kede oludije fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Peter Mbah gẹgẹbi
olubori idibo sipo gomina ni ipinlẹ Enugu.

INEC kede pe Mbah ni iboẹgbẹrun lọna ọgọjọ ati
ẹgbẹrin o le aadọrun ati marun un (160, 895); lati fi ajulọ han oludije ẹgbẹ oṣelu
Labour party, LP Chijioke Edeoga to ni
ibo ẹgbẹrun mẹtadinlọgọjọ ati ẹẹdẹgbẹta o leaadọta ati meji (157,552) nibi ibo
gomina to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Ibo ẹgbẹrun mẹrinla ati ọrinlelẹẹdẹgbẹta o din
marun (14,575) ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ninu esi idibo naa.

Copyright: b

Alakoso eto idibo naa, to tun jẹ giwa fasiti imọ
nipa eto ọgbin, Michael Okpara University of Technology Umudike, Ọjọgbọn
Maduebibisi Ofo-Iwe kede esi idibo nipinlẹ naa lẹyin ti ajọ INEC ti kọkọ so ikede
esi idibo nibẹ rọ fun nnkan bii wakati mẹrinlelogun nitori awọn kudiẹkudiẹ kan.

Esi idibo ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ni ajọ INEC ti
kede bayii ninu ipinlẹ mejidinlọgbọn ti idibo ti waye lọjọ Satide.

APC lo bori lawọn ipinlẹ marundinlogun, PDP wọle
ni ipinlẹ mẹsan, LP wọle ni ipinlẹ kan, NNPP si wọle ni ipinlẹ Kano nikan.

Gomina meje labẹ ẹgbẹ oselu APC lo pada fun
saa keji nigba ti meji n pada fun saa keji labẹ aṣia PDP

Copyright: pdpnigeria