Àwọn adigunjalè ṣèkọlù sí ilé adẹ́rìínpòṣónú, Woli Agba n’Ibadan

Ayo Ajewole

Oríṣun àwòrán, Woli Agba/Instagram

Adẹrinpoṣonu, Ayo Ajewole, ti ọpọ mọ si Woli Agbe ti kede pe awọn adigunjale ṣe ikọlu si ileegbe rẹ to wa niluu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.

Ajewole lo kede isẹlẹ naa lori opo ayelujara rẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi o ṣe ko oun ati idile rẹ yọ ninu ewu awọn adigunjale.

Ileeṣẹ BBC kan si Woli Agba lati mọ bi isẹlẹ naa ṣe waye.

Ọkan lara osojumikuro to wa nibẹ lasiko ti isẹlẹ naa waye sọ pe ago meji oru ni awọn adigunjale naa wọle tọ wọn wa.

“Bi ago meji orun ni a gbọ iro ibọn, ti a si n gbọ ariwo ni ile to wa ni ẹgbẹ ọdọ wa, ṣaadede ni wọn wọ ninu agbala wa.

“Ko pẹ si asiko naa ni wọn wọlẹ to wa wa, ti wọn si gba awọn dukia.

Eeyan to ba BBC Yoruba sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ ka da orukọ rẹ ṣalaye pe wọn ko ṣe ẹnikẹni leṣe rara ati pe kete ti wọn gba awọn dukia naa, ni wọn jade.”