NÍ YÀJÓYÀJÓ Ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi gbẹ̀mí arìnrìnàjo 60

Copyright: Reuters

O to eeyan ọgọta to n rin irinajo lori ọkọ oju omi lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ akero oju omi doju bolẹ.

Eeyan mẹrindinlogoji, pẹlu awọn ọmọde ni wọn ri dola ni ẹgbẹ omi lorilẹede Cape Verde.

Gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ oju omi akero lo ti wa ni lori fun oṣu kan, ti igbagbọ si wa pe ọmọ orilẹede Senegal ni wọn.

Ijọba orilẹede Cape Verde ti kesi ajọ agbaye lati wa nnkan se lati bi wọn eeayn se gbiyanju lati wọ orilẹede kan tabi omiran ni ọna aitọ, ki sisọ ẹmi nu le dikun.

Agbẹnusọ ajọ agbeye lori irinajo IOM ni awọn eeyan ti wọn ko ba isẹlẹ naa lọ ni ọmọde mẹrin, ti wọn wa ni ọmọ ọdun mejila si mẹrindilogun.

Ajọ to n oke okun lorilẹede Senegal ni ọkọ oju omi akero naa lo gbera kuro ni abule pajepaje lorilẹede Senegal, Fasse Boye lọjọ kẹwaa oṣu keje pẹlu eeyan kan le ni ọgọrun un.

Moda Samb, oloselu ni abule naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe pupọ awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi naa lo jẹ agbalagba, ti pupọ awọn idile si n reti iroyin boya awọn eeyan wa laye.

Ajọ ọhun ni awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu orilẹede Cape Verde lori bi awọn to ye isẹlẹ naa yoo se pada wale.

Awọn arin irinajo yooku lo wa lati orilẹede Sierra Leone ati eeyan kan lati Guinea-Bissau

Jose Moreira, osisẹ ilera ni Sal ni awọn to farapa nibi ijamba naa ti n gba itọju, ti wọn si n se itọju wọn nipa ti ounjẹ.

Minisita fun eto ilera, Filomena Goncalves ni: “A mọ isoro to wa ni gbogbo agbaye ti wọn eeyan fẹ kuro nibi kan lọ si ibi kan, a ti lati fọwọ sowọpọ gbogun ti isoro yii ni”