Ìgbìmọ̀ IFÁ àgbáyé wọ́gilé Ọdún Ìṣẹ̀ṣe nílùú Ilorin

Aworan awọn Onisẹse

Oríṣun àwòrán, other

Ẹgbẹ igbimọ agbaye fun IFA ti kede ipiinu rẹ lati wọgile sise Ọdun Isẹse niluu Ilorin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara.

Ikede yii wa ninu atẹjade ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Oluwo Solagbade Popoola buwọlu fun awọn akọroyin niluu Abuja, to si ni awọn gbe igbesẹ naa lati yago fun rogbodiyan.

Bakan naa ni ẹgbẹ fẹsun kan Ileeṣẹ Ọlọpaa pe wọn se ojusaju, ti wọn si korira awọn ẹlẹsin Ibilẹ.

Popoola, ninu atẹjade naa salaye pe lẹyin ipade ti awọn se pẹlu Ileeṣẹ Ọlọpaa lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, lori erongba lati se Ọdun Isẹse niluu Ilorin, ti ipade si tako sise ọdun naa.

Ẹgbẹ igbimọ agbaye fun IFA wa tun ṣalaye siwaju sii pe awọn ṣe ipade pẹlawọn ọlọpaa lori rukerudo naa, “abajade ipade naa ni wọn ti gbẹsẹ le ṣiṣe ajọdun naa pẹlu awawi pe hilahilo ti n wa ni ipinlẹ ọhuin.

“A ko ṣai mọ pe awọn ọlọpaa laṣẹ lati fi idi ofin mulẹ ati lati rii daju pe abo to peye wa fun ẹmi ati dukia ilu.”

Ẹgbẹ naa ni awọn agbẹjọro wọn ti foju wo igbesẹ ti ọlọpaa gbe naa gẹgẹ bi eyi to tako ẹtọ ọmọniyan

” Igba akọkọ niyi ti ọlọpaa yoo gbẹsẹ le apejọpọ ẹsin ninu itan ipinlẹ Kwara.

A ko le sọ sugbọn a ni lati dabo bo awọn eeyan lọwọ Ikọlu gẹgẹ ẹlẹsin alaafia

Popoola tẹsiwaju pe awọn gbe igbesẹ yii lati jẹ ki alaafia jọba ati lati dabo bo awọn lọwọ nnkan ti wọn ni awọn ko le sọ boya ikọlu ati itaẹjẹ silẹ le waye lasiko tabi lẹyin ọdun naa.

“Pẹlu bi nnkan se n lọ, a pinnu lati dawọ duro lori sise Ọdun Isẹse.

“A rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati tẹle igbesẹ yii.”

Ẹ gbé àjọ̀dún yín jìnà réré sí ìlú Ilorin – Àgbáríjọpọ̀ Alfa ní Kwara ṣèkìlọ

Àgbáríjọpọ àwọn Alfa ati ijọ Musulumi ni ipinlẹ Kwara ti ṣekilọ fun awon to n gbero lati se ayẹyẹ ọdun ifa ni ilu Ilọrin, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara pe ki wọn ni iyipada ọkan.

Awon Alfa ọhun sọ wi pe awon ko ni gba ayẹyẹ ọdun ifa laaye ni gbogbo ilẹ Ẹmireeti, eyi to ko ijọba ipinlẹ Asa, Moro, Ilorin East, Ilorin West ati Ilorin South sinu.

Akọwe agba ijọ naa, Adajọ fẹyinti Salihu Mohammed lo fi ọrọ naa lede ni ile Alaga ijọ naa, Imam agba ti ilu Ilọrin, Sheik Mohammed Bashir Salihu.

Awon Alfa agba to wa nibẹ ni Imam Gambari, Ajanasi Agba, Sheikh Yusuf Pakata, Ojọgbọn Badmas Yusuf, awon adajọ fẹyinti meji, Idris Haroon ati Ola AbdulKadir; aarẹ to ti jẹ sẹyin fun Ilorin Emirate Descendants Progressive Union (IEDPU), Alhaji AbdulHamid Adi ati awon aṣoju Imam ati Alfa kaakiri ijọba ibilẹ merindinlogun ni ipinlẹ Kwara.

Apapọ awọn Alfa

O tun sọ pe bi awọn ọdọ International Council for Ifa Religion (ICIR), ṣe n tẹmpẹlẹ mọ lati ṣe ọdun naa ni ipilẹ Kwara ni ogunjọ osu Kẹjọ jẹ eyi ti o mu ewu dani fun ẹmi ati dukia awọn olugbe Kwara.

“Eyi lo faa ti afi n rọ ijọba Kwara, ati awon ti ọrọ naa kan ki won bawa rawọ ẹbẹ si ajọ ICIR ati awon yooku lati gbe ọdun won jina rere si Ilọrin nitori pe ṣiṣe ọdun naa le da omi alaafia ilu ru.

“Gẹgẹ bi ilu ati agba ti a jẹ ni ile kọọkan, amọ igbaradi ẹgbẹ awon ọdọ lati ma jẹẹ ki eto naa waye ni Ilọrin.

“Ni ti wọn, ọdun naa yoo ba alafia ati idakẹrọrọ ilọrin jẹ gẹgẹ bi o ṣe jẹ ikọlu si ọla, asa ati iṣe ilu Ilorin.”

Awọn Imamu ilu Ilorin

Muhammed rọ awon ọdọ musulumi lati ṣe suuru, o si tun rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq lati pasẹ fun ajọ eleto aabo, ki won wa nnkan ṣe si ọrọ naa ni kiakia.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ti rọ awọn oniṣẹṣe lati wọgile ọdun iṣẹṣe eyi ti wọn n gbero lati ṣe ni ilu Ilorin.

Kọmiṣọna ọlọpaa Kwara, Ebunoluwarotimi Adelesi ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, Ajayi Okasanmi fi lede lọjọ Aje ni awọn ti ba awọn oniṣẹṣe sọrọ lori ewu to wa ninu ṣiṣe ọdun ti wọn n gbero naa.

Adelesi ni gbogbo awọn iwadii awọn fi han pe eto aabo to peye ko si fun ọdun naa nitori naa awọn ti gba wọn ni imọran lati lọ ṣe ọdun wọn ni ipinlẹ miiran dipo ṣiṣe ni Ilorin.