NÍ YÀJÓYÀJÓ Ìfẹ̀họ́núhàn wáyé ní Paris, Amsterdam, Dublin, Toronto láti ṣàtílẹyìn fún àwọn àra China

Copyright: BBC

Agbebọn kan ti pa eeyan to to mẹwaa ni ile itaja nla
Warlmart to wa ni agbegbe Chesapeake, virginia lorilẹede Amẹrika.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ ọkunrin kan ti ireti wa pe oun ni
alamojuto yara ikẹrupamọ si ni ile itaja naa ṣina ibọ́n bolẹ, doju rẹ kọ ara rẹ.
O si ti ku bayii.

Oju opo Twitter ilu Chesapeake
fi sita pe “ọlọpaa ti fi aridaju iṣẹlẹ bi kunrin kan ṣe yinbọn mulẹ ati ọpọlọpọ
ẹmi to baa lọ ni ile itaja Warlmart”.

Ko tii si ẹkunrẹrẹ iroyin nipa rẹ amọ ọlọpaa kan jẹ ko di
mimọ pe ko din ni eeyan mẹwaa to ku ti ọpọlọpọ si farapa. Ko tii si aridaju
ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Ọlọpaa sọ fun awọn
oniroyin pe ikọlu naa waye ni nnkan bii ago mẹwa kọja iṣẹju mejila ago orilẹede
wọn.

Agbẹnusọ Leo Kosinski sọ pe igbagbọ ni pe ibọn yinyin naa ṣẹlẹ
ninu yara iko nkan pamọ si ti afurasi naa si da iṣẹ ọjun ṣe.

Àwọn to ṣoju wọn koro sọrọ

Ile itaja Warlmart ni iṣẹlẹ naa ba awọn lojiji ti wọn si ni
awọn ti n ṣiṣẹ pọ pẹlawọn agbofinro.

Awọn aworan to jade lori ayelujara ṣafihan aduru awọn ọlọpaa
to wa nibẹ bẹẹ si ni fidio mii ṣafihan eeyan ti iṣẹlẹ ṣoju rẹ to wọ aṣọ iṣẹ
Warlmart to si n ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ.

O ni oun kuro ninu yara awọn oṣiṣẹ, mọnija kan si wọ ibẹ to
si ṣina ibọ́n bo ilẹ.

“O ba ni ninu jẹ pe a padanu awọn eeyan wa,” ọkunrin naa sọ
bẹẹ to n ṣalaye pe oun ko mọ iye awọn akẹgbẹ rẹ ti ibọn ba.

Agbẹnusọ kan fun ile iwosan Sentara Nortfolk n sọ fun ileeṣẹ
amohunmaworan kan, WAVY-TV pe eeyan marun ni wọn n tọju lọwọ.

Obinrin kan naa sọ fun Tẹlifisan ọhun pe aburo oun to jẹ ẹni
ogun ọdun to n ṣiṣẹ nile itaja naa wa lara awọn ti wọn ṣẹṣẹ yinbọn ba lẹyin iṣẹju
mẹwa to wọ ẹnu iṣẹ.

Ṣugbọn o ni aburo oun ri aaye ba awọn ẹbi rẹ sọrọ to si fi
atẹjiṣẹ ranṣẹ – o ni “eyi fi ni lọkan balẹ.”

Obinrin mii to ba CNN sọrọ, Joetta Jeffery sọ pe iya oun wa
ninu ile naa nigba ti ikọlu ọhun waye to si tiraka lati fi atẹjiṣẹ ranṣẹ, ko
farapa amọ o wa ninu ipaya.

Awọn eekan oloṣelu ni Virginia ti n fi ọrọ sita nipa bi iṣẹlẹ
naa ṣe ba wọn lọkan jẹ.

Bakan naa lọdun 2019, iṣẹlẹ ibọn yinyin paayan waye ni ile
itaja Warlmart ni ilu El Paso ni Texas to si mu ẹmi eeyan mẹtalelogun lọ.

Iṣẹlẹ to ṣẹ ṣẹlẹ yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti agbebọ́n kan ṣina
bolẹ ni ile ijo awọn onibalopọ akọsakọ ni Colorado, USA ti o si pa eeyan marun
ati ti eyan mẹtadinlogun mii farapa.