Ẹ yẹ̀bá kúrò láàfin ná, mó fẹ́ ṣèwádìí bí ẹ ṣe d’órí ìtẹ́, Adeleke pàṣẹ fún àwọn ọba Ikirun, Iree àti Igbajọ

Ademola Adeleke

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti paṣẹ pe ki wọn o ti aafin ọba ilu Ikirun, Iree ati Igbajo pa.

Ọjọ Aje, to jẹ ọjọ́ akọkọ rẹ lẹnu isẹ, ni Gomina Adeleke pa àṣẹ naa, to si ni kí awọn oṣiṣẹ alaabo gbakoso wọn.

Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, agbẹnusọ fun gomina, Mallam Olawale Rasheed, sọ pe gbogbo àwọn ọba, ati ìfinijoyè míì to waye lẹyin ọjọ́ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ti di fifa igi lé titi atungbe yẹwo wọn yoo fi waye.

“Gbogbo ọba ti ìjọba ipinlẹ Osun fi jẹ lẹyin ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ni àṣẹ ti wà lati ṣe atungbe yẹwo wọn yóò waye”.  

“Eyi jẹ ọna lati ríi daju pe wọn tẹle ila oye jijẹ, to fi mọ àṣà ati ìṣe, to wa fun òye kọọkan.”

Mallam Olawale Rasheed sọ pe gomina ti da eto ọba jíjẹ Akirun ti Ikirun, Aare ti Ire ati Ọwá ti Igbajo, duro nitori ki opin le ba rògbòdìyàn to n waye nibẹ.

Àṣẹ naa tun sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ duro ninu awọn aafin ìlú naa titi di asiko ti ijọba bá ṣi wọn pada.

Lati igba ti gomina to ṣẹ̀ṣẹ̀ kuro nipo, Gboyega Oyetola ti yan ọba si àwọn ilu naa, paapaa Ikirun, ni ija igboro ti n waye.

O si ti yọrí si ifarapa ọpọ eeyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn dukia si bajẹ.

Rogbodiyan ti n waye lori ọba ni Ikirun ṣaaju asiko yii

Niluu ikirun, ni ọsẹ to kọja, wahala Ọlọbade gba ọna miran yọ lẹyin ti awọn janduku kan ṣe ikọlu si aafin Akinrun ti ilu Ikirun, ti wọn si dana sun un.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe bii osẹ diẹ sẹyin ti awọn eeyan ilu ọhun ṣe ifẹhonuhan lori bi wọn ṣe yan ọba tuntun, wọn gbe adagagodo si ẹnu ọna aafin, eyi ti ko fun Ọba tuntun ni anfani lati wọle si aafin.

Bakan naa ni iroyin ọhun ni awuyewuye miiran bẹ silẹ ni ọsẹ to lọ, lẹyin ti Ọba ati awọn ọlọpaa fẹ wọle si aafin, ti wọn si ṣina bolẹ lati ṣeruba awọn olufẹhonuhan ṣugbọn ti ibọn ba ọkùnrin kan, to si jade laye.

O to eeyan mẹrin miiran to farapa yanayana nigba ti awọn ọlọpaa fẹ gba akoso Aafin naa.

Àwọn àṣẹ míì ti Adeleke tun pa

Yàtọ̀ si ti oyè ọba, Gomina Ademola Adeleke tun pàṣẹ pe owo ko gbọdọ wọlé tabi jade ninu àwọn àsùnwọ̀n ìjọba ipinlẹ Osun.

Bakan naa lo tun wọgile gbogbo igbani ṣíṣẹ́ to waye lẹyin ọjọ kẹtadinligun, oṣu Keje.

Eyi ko yọ àwọn olori ileeṣẹ ati àwọn Àjọ to jẹ ti ìjọba, ti iyansipo wọn waye lẹyin asiko naa, silẹ.