Akẹ́kọ̀ọ́ girama mẹ́ta fípá bá akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún 14 lòpọ̀ ní Akure

Aworan eeyan kan to fẹ fipa ba eeyan lo

Oríṣun àwòrán, other

Awọn akẹkọọ girama  mẹta kan ti wọn gbaga ọlọpaa nipinlẹ ondo fun ẹsun gbigbimọ pọ fi ipa ba akẹkọọ ẹgbẹ wọn lo pọ.

Iroyin sọ pe iwe karun girama lawọn akẹkọọ mẹta naa wa ni ile ẹkọ girama Akurẹ High School ni ilu Akurẹ.

Iroyin sọ pe ọmọ ọdun mẹrinla ni akẹkọọ ti wọn fi ipa ba lopọ naa, ati pe o ti pẹ ti awọn akẹkọọ naa ti n yọ akẹkọbinrin naa lẹnu pe awọn fẹ maa baa dọrẹ ikọkọ ṣugbọn ti ko jẹ wọn lohun.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ọmọdebinrin naa lọ ṣe igbọnsẹ ni ibi igbo kan ninu ọgba ileewe naa ni awọn afurasi naa fi kaa mọ ọna ti wọn si fi ipa baa ṣe pọ.

Gẹgẹbi ohun ti a tun gbọ, nigba ti ọmọdebinrin naa wọ kilasi pada ni awọn akẹgbẹ rẹ ri abawọn ẹjẹ lara aṣọ ile ẹkọ rẹ ti wọn fi figbe ta.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, SP Funmi Ọdunlami to fi idi ọrọ naa mulẹ ṣalaye pe wọn ti fi panpẹ ofin gbe awọn akẹkọ naa.

Bakan naa ni iroyin tun sọ pewọn ti ko awọn afurasi naa lọ si ahamọ awọn ọdaran ọmọde titi ti iwadi ati igbẹjọ wọn yoo fi waye.