‘Àwa Ọlọ́pàá ò lè sọ bóyá lóòtọ́ ọmọ Yahoo ló ju òkú obìnrin s’ẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ẹní bá mọ̀ọ́ kó fojú hàn’

Ami idanimọ Ọlọpaa Naijria

Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fesi lori oku arabinrin kan ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ ati ti ko sẹni to mọ awọn to wa gbe oku rẹ ju si ẹgbẹ ṣọọṣi kan.

“Nigba ti a debẹ ao ri egbo kankan lara rẹ, ko sohun tọ jọ pe wọ́n ṣaa ni nkankan tabi fun un lọrun”.

Oku arabinrin nilẹ

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ọlọpaa Ondo, Odunlami Ibunkun ṣalaye pe lowurọ ọjọ Iṣegun ni Pasitọ ṣọọṣi naa lọ si agọ ọlọpaa to wa lagbegbe ọhun pe awn to wa ṣe adura mọju sọ pe wọn dede ri oku to ku.

Odunlami ṣalaye pe o ṣe ni laanu pe awọn eeyan kan maa n dede la ẹnu sọ ohun to ba wu wọn bi nkan ba ti ṣẹlẹ. O sọ eyi tori ko si ẹni to rii nigba ti wọn n gbee sibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

“Gbogbo eeyan kan dede ji ba oku arabinrin yẹn ladugbo yẹ ni ti awọn kan si dede n dabaa ohun to ṣẹlẹ pe boya wọn loo fun nkan ni tabi awọn ọmọ Yahoo ni”.

Alukoro ọlọpaa ni nkan ti awọn kan ri nibẹ ni pe wọn ba ọpọ idọti to yii ka. Nigba tawọn ọlọpaa de bẹ wọn ni ko si ami kankan pe wọn yọ nkankan lara rẹ tabi fun un lọrun”.

“A ti gbé òkú obìnrin tí wọ́n jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì l’Akure lọ Mọ́túárì, a si ti fi ikede sita pẹlu awọn oṣiṣẹ ọfiisi ijọba pe ki awọn eeyan to ba mọ ọ wa lati sọ tabi awọn to n wa eeyan wọn kan ki wọn wa si agọ Ọlọpaa lati yẹ oju rẹ wo”.

Oku obinrin ti wọn ba nilẹ

Lori ohun ti ọlọpaa ti ṣe ati boya wọn ti ṣe ayẹwo nilana ti imọ iṣegun oyinbo, alukoro ọlọpaa ni oun ko le sọ boya wọn ti ṣe ayẹwo yẹn.

“Nkan ṣoṣo to jẹ igbesẹ ti a n gbe bayii ni pe a n kede pe bi ẹnikẹni ba mọ ẹbi ati ara rẹ ki wọn yọju si wa ni agọ wa ka jọ lọ woo ni mọṣuari”.

Ọga ọlọpaa ni ohun ti wọn n sọ pe wọn ri awọn nkan bii kankan ibilẹ, foonu, awọtẹlẹ ati oogun, o ni iru ọrọ bayii, ọrọ okere lo maa n di amọ awọn ọlọpaa ko ri nkan to jọ bẹẹ lẹgbẹ rẹ ju panti to yii ka lọ.