Nàíjíríà kò tíì pegedé tó láti ní Ọ́lọ́pàá ìpínlẹ̀ – Ọ́gá àgbà ọ́lọ́pàá

Aworan Aarẹ Bola Tinubu ati Kayode Egbetokun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/Facebook

Ọgaagba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria, IGP Kayode Egbetokun ti sọ pe Naijiria ko tii ṣetan lati ni ọlọpaa ipinlẹ, bo tilẹ jẹ wi pe iṣoro eto aabo pọ lọwọ yii.

IGP Egbetokun fidi ọrọ yii mulẹ nibi apero kan to da lori lilo ọlọpaa ipinlẹ gẹgẹ bi ọna lati mu ki alaafia jọba ni Naijiria.

Eto naa waye niluu Abuja lọjọ Aje ọjọ kejilelogun oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii.

Egbetokun ti AIG Ben Okolo ṣoju rẹ nibi apero naa sọ pe ‘’erongba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni pe a ko tii to ni ọlọpaa ipinlẹ gẹgẹ bi orilẹede.

Ara awọn iṣoro ti yoo koju idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ni pe igbimọ alaṣẹ awọn ipinlẹ eleyii ti gomina jẹ adari rẹ le ṣi agbara lo pẹlu ọlọpaa ipinlẹ.

Awọn gomina le maa lo ọlọpaa ipinlẹ yala fun anfani ara wọn tabi lati tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.

Ati pe rogbodiyan le maa waye lori ẹni tawọn ọlọpaa yoo maa gba aṣẹ lọwọ rẹ.’’

“Tinubu atawọn gomina fẹnu ko nibi ipade naa lati da ọlọpaa ipinlẹ silẹ”

Lẹyin to sọ pe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ le ma ṣiṣẹ lọwọ yii ni Naijiria, ọga ọlọpaa Naijiria ko ṣai sọ awọn ọna ti ileeṣẹ ọlọpaa fi le lagbara sii lati koju iṣoro eto to mẹhẹ.

‘’Akọkọ ni pe ijọba le da ajọ aabo araẹni laabo ilu(NSCDC) ati ajọ ẹṣọ oju popo(FRSC) pọ ki wọn si jẹ ẹka kan labẹ ileeṣẹ ọlọpaa,’’ Egbetokun lo sọ bẹẹ.

Ọgaagba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria tun ṣalaye pe o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa maa gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan siṣẹ ọlọpaa lọdọọdun ni ibamu pẹlu alakalẹ ajọ iṣọkan agbaye, UNO lori ileeṣẹ ọlọpaa awọn orilẹede.

Bakan naa ni o sọ pe idanilẹkọọ loorekoore fawọn ọlọpaa yoo ṣe iranwọ lori ati gbogun ti iṣoro eto aabo to n koju Naijiria lọwọ yii.

Lai ṣe ani-ani, erongba ọgaagba ọlọpaa tako ti Aarẹ Bola Tinubu lẹyin ti o ṣe ipade pọ pẹlu awọn gomina laipẹ yii lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lati le koju eto aabo to mẹhẹ.

Minisita eto iroyin, Mohammed Idris sọ fawọn akọroyin pe Tinubu atawọn gomina fẹnuko nibi ipade naa lati da ọlọpaa ipinlẹ silẹ.

Amọ, o ṣalaye pe ipade mii yoo tun waye lori ọrọ naa.

Ọlọpaa ipinlẹ yoo ṣe iranwọ nla lori aabo ṣe mẹhẹ ni Naijiria – Goodluck Jonathan

Ẹwẹ, aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan toun naa wa nibi apero ọhun sọ pe ọlọpaa ipinlẹ yoo ṣe iranwọ nla pẹlu bi eto aabo ṣe mẹhẹ ni Naijiria bayii, bo tilẹ jẹ pe o ni awọn ipenija rẹ.

Jonathan ni bi iṣẹlẹ ijinigbe ati iwa ọdaran ṣe n gbilẹ sii n fidi rẹ mulẹ pe Naijiria nilo ọlọpaa ipinlẹ.

Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima ti oun naa wa nibi apero ọhun sọ pe Aarẹ Bola Tinubu koni beṣu bẹgba lati ro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lagbara lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.

Igbakeji aarẹ ni Tinubu ṣetan lati sẹ agbeyẹwo koko to jade nibi apero to waye lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ.