Bobrisky pín àga ọ̀fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó tún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Ọkunrin to maa n mura bii obinrin, Idris Olanrewaju Okuneye, ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tako ẹwọn oṣu mẹfa ti ile ẹjọ da fun lẹyin to jẹbi ẹsun titabuku owo naira.

Idris, ti ọpọ mọ si Bobrisky, lo pe ẹjọ naa lati ọwọ agbẹjọro rẹ, Bimbo Kusanu, pe ki ile ẹjọ yi idajọ ẹwọn to fun oun pda, ko si fun oun lanfani lati san owo itanra dipo ẹwọn.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni adajọ Abimbola Awogboro ti ile ẹjọ giga ilu Eko ṣedajọ ẹwọn oṣu mẹfa lai si anfani lati san owo itanran kankan fun Bobsirky lẹyin to jẹbi ẹsun titabuku owo naira.

Nigba to n dajọ ọhun, adajọ naa ni idajọ naa yoo kọ awọn araalu to ba fẹ maa wu irufẹ iwa bẹẹ lọgbọn.

Ṣaaju idajọ yii lọjọ karun un, oṣu Kẹrin yii kan naa ni ọdaran ọhun ti kọkọ sọ pe oun jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan oun.

Ninu iwe ipẹjọ kotẹmilọrun rẹ, ọdaran naa sọ pe ile ẹjọ fun oun ni ijiya to pọ julọ fun ẹsẹ ti oun ṣẹ bo tilẹ jẹ pe oun ko ni akọsilẹ kankan ṣaaju iṣelẹ naa gẹgẹ bii arufin.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, idajọ ọhun waye lai si oju aanu kankan fun oun, eyii ti ko si ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin Administration of Criminal Justice, ACJA, ti orilẹede Naijiria.

O fi kun pe adajọ naa ko tun wo ti pe oun ko fi akoko ile ẹjọ ṣofo latari bi oun ṣe tete sọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Bobrisky fi aga ta ọgba ẹwọn lọrẹ

Ẹwẹ, laarin nnkan bii ọsẹ meji pere lọgba ẹwọn, iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe Bobrisky ti fi awọn aga kan ta ọgba ẹwọn Kirikiri to wa lọrẹ.

Ninu aworan aga naa to gba ori ayelujara, wọn kọ akọle “si ileeṣẹ ọgba ẹwọn Naijiria lati ọwọ idris Okuneye Bobrisky” si lara.

Iroyin to gba igboro nipa awọn aga naa ni pe o wa fun agbegbe ti awọn alejo yoo maa joko si lọgba ẹwọn naa.