Gbogbo ìgbà tí mo gbé ìpèníjà dé iwájú ìyàwó Ààrẹ Tinubu ló ń bá mi wá ọ̀nà àbáyọ – Gómìnà Ademola Adeleke

Oluremi Tinubu

Oríṣun àwòrán, Sen Oluremi Tinubu, CON/X

Gbogbo ìgbà tí mo bá tí ní ipenija ní aya Aarẹ orilẹede Naijiria Oluremi Tinubu má fí mí lọ́kàn balẹ to si mọ wa ọna àbáyọ sì ipenija náà.- Gómìnà Ademola Adeleke.

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke ti ṣalaye pe gbogbo igba ti oun ba ti ni ipenija, ọkan pataki lara aawọn ti o maa n ṣugba oun ni iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Olurẹmi Tinubu jẹ.

Ọrọ yii yoo jẹ kayefi fun ọpọlọpọ pẹlu bi o ṣe jẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ni awọn mejeeji yii ti jade wa.

Ẹgbẹ oṣelu APC ni aya aarẹ ti jade wa ti Gomina Adeleke si ṣẹ wa lati ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ohun miran ti o mu ọrọ yii ya ọpọ lẹnu naa ni pe oludije ẹgbẹ oṣelu APC ti Ademọla Adeleke fi idi rẹ janlẹ ni idibo gomina Ọṣun, iyẹn Gboyega Oyetọla, jẹ ibatan Aarẹ Tinubu to jẹ ọkọ Sẹnetọ Olurẹmi.

Amọṣa, ọrọ Gomina Adeleke yii fihan pe wọn ti pa gbogbo dukuu idibo ti si ẹgbẹ kan lati ṣe ohun to tọ fun idagbasoke ilu.

Gomina Adeleke pẹlu Sẹnetọ Tinubu

Gomina Adeleke sọ ọrọ yii lasiko ti aya aarẹ orilẹede Naijiria ṣe abẹwo si ipinlẹ Ọṣun ni Ọjọ Iṣẹgun.

Gomina Ademola Adeleke tọka si Aya Aarẹ Naijiria gẹgẹ bii iya rere ati ẹni to ni ifẹ ọmọ lakeji to si fẹ ìlọsíwájú orilẹede Naijiria ati Ipinle kọọkan.

Gomina Adeleke tun tesiwaju wi pe, Oluremi Tinubu jẹ ẹni to ni itẹlọrun ati ẹni to ni ifarada gidigidi; to si wa fi da a loju wi pe, ijọba oun ṣe tan lati fọwọsowọpọ lati ri daju wi pe, awọn ọmọ Obìnrin nipinle Osun ṣe e mu yangan lawujọ, orilẹede Naijiria ati ni gbogbo agbaye.

Mo fẹ́ ìfọ́wọ́sowọ́pọ̀ àwọnlọ́balọ́ba fún àṣeyọrí Ààrẹ Bola Tinubu àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá – Oluremi Tinubu.

Aya Aarẹ Tinubu

Aya Aarẹ orileede Naijiria, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu tun ba gbogbo awọn oriade nipinlẹ Ọsun ṣe ipade idakọnkọ nibi to ti pe fun iṣọkan laaarin ọmọ Yoruba fun aṣeyọri Bọla Tinubu gẹgẹ bii ààrẹ Naijiria.

Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu rọ awọn ọbalaye gbogbo ni ilẹ Yoruba lati fi ẹmi ifẹ han lagbegbe wọn ki alaafia le jọba lorilẹede Naijiria.

Aya Aarẹ Naijiria ke sawọn oriade naa lati maṣe fi aaye gba awọn ọdọ to le fẹ da omi alaafia orilẹede Naijiria ru lagbegbe wọn.

Ipò obìnrin àkọ́kọ́ di ariwo, Titilola ni àbí Ngozi ní ‘First Lady’ l‘Osun?

Aworan awọn iyawo gomina Ọṣun mejeeji ti wọn n ki Iyawo aarẹ kaabọ s'Ọṣun

Oríṣun àwòrán, BBC

Ariyanjiyan nipa ta ni obinrin akọkọ (First lady) ninu iyawo meji ti Gomina ipinlẹ Ọsun, Ademọla Adeleke ni, n foju han bayii lori ayelujara.

Erelu Ngozi Abẹni Adeleke ati Oloye Abilekọ Titilọla Adeleke ni iyawo meji ti Gomina Ademọla Adeleke, tii se gomina ipinlẹ Osun ni, tawọn eeyan mọ.

Lọjọ ayẹyẹ iburawọle gomina Ademola Adeleke, tii se ọkọ wọn, awọn obinrin mejeeji yii lo rọgba yi ọkọ wọn ka, ti wọn si fi oju han bii aya gomina nipinlẹ Osun.

Ọpọ eeyan fi ọwọ lẹran, maa woye ibi ti igi ọrọ naa yoo wo si nitori orisa jẹ n pe meji obinrin ko denu, ti wọn si n reti ki ariwo sọ laipẹ laarin awọn aya gomina mejeeji naa.

Lootọ ni alaafia ti wa lati igba ibura ọkọ wọn amọ sadede ni ariwo ta nipa bi awọn aya gomina mejeeji se lẹ iwe ikede ọtọọtọ lati ki aya aarẹ, Oluremi Tinubu kaabọ si ipinlẹ Osun.

Eyi si lo fa a tawọn eeyan fi n beere pe ta ni ‘First lady’ eyiun obinrin àkọ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọṣun gan-an?

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ṣaaju ni ikede ti wa pe lonii yii, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹrin ọdun 2024 ni iyawo aarẹ yoo balẹ siluu Oṣogbo.

ifilọlẹ ileewe Alternative High School fawọn akẹkọọbinrin, eyi to wa ni Oke D.O, Ilesha Road, Osogbo pẹlu awọn akanṣe iṣẹ mi-in, ni iyawo aarẹ wa se..

Ṣugbọn ṣe ni iwe ikede lọ́nà méjì ti ọfiisi awọn iyawo gomina mejeeji wa, ti wọn si n ki Iyawo aarẹ kaabọ.

Atẹjade lati ọwọ Erelu Ngozi, tọka si ọfiisi obinrin akọkọ l’Ọṣun, bakan naa si ni eyi ti Titilọla naa se, n pe ara rẹ ni First lady Ọṣun.

Eyi lo mu awọn eeyan maa beere, pe ta a ni Obinrin akọkọ ninu Ngozi ati Titilọla Adeleke, ti wọn jẹ́ aya gomina Osun.

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke

Gómìnà Adeleke sọ̀rọ̀, ó ní Titilọla lobìnrin àkọ́kọ́ l’Ọ́ṣun

Bi awuyewuye naa ṣe gba ori afẹfẹ ni Agbẹnusọ Gomina Adeleke, Ọlawale Rasheed, kede pe Abilekọ Titilọla Adeleke ni obinrin akọkọ l’Ọṣun.

O ni Titilọla ni yoo gba Iyawo aarẹ lalejo, ki i ṣe Ngozi.

Atẹjade naa sọ pe ko ruju rara, pe Titilọla ni ipo naa wa fun latilẹ.

O ni awọn ti wọn fẹẹ da rúgúdù silẹ ni wọn n gbe atẹjade awuruju jade lorukọ Ngozi, ati pe wọn ti fọwọ ofin mu ẹni naa.

Ngozi ko mọ nnkan kan nipa atẹjade naa bi agbẹnusọ gomina ṣe wi.

Atẹjade lati ọdọ Gomina Adeleke sọ pe, ‘’ Fun alaye kikun, Oloye Abilekọ Titilọla Adeleke, Obinrin akọkọ nipinlẹ Ọṣun, yoo gba iyawo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lalejo lọla(oni), gẹgẹ bi aṣẹ lati ọdọ gomina.

‘’Eyi o ruju’’

O fi kun un pe ko sija laarin awọn iyawo gomina mejeeji, alaafia ni.

Ẹnikan to mọ bo ṣe n lọ nipa awọn iyawo mejeeji yii nipinlẹ Ọṣun, ṣalaye pe Titilọla ni iyawo akọkọ ti Gomina Adeleke fẹ.

O ni wọn ti pin ipo ti kaluku yoo maa dimu to ba di iṣẹ ilu fun wọn latilẹ.

Eyi to fi han pe Titilọla yoo maa mojuto eto ijọba apapọ, nigba ti Ngozi yoo maa mojuto ti ipinlẹ Ọṣun lasan.

O ṣoju mi koro to ni ka forukọ boun laṣiiri naa sọ pe Ngozi naa ni ọfiisi tiẹ bii iyawo gomina nipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn iṣẹ ipinlẹ naa lo le fi ṣe, ki i ṣe tijọba apapọ bi eyi.