Kí ló ń fa èdè aìyedè nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun lórí àkọ́sọ̀ ọ̀rọ̀ tí Gómìnà Adeleke sọ?

Aworan idanimọ ile aṣofin ipinlẹ Ọṣun pẹlu aworan gomina Ademọla Adeleke

Oríṣun àwòrán, Facebook/State of Osun Assembly/Twitter/Ademola Adeleke

Edeaiyede kan n waye ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun lọwọ lori awọn ohun ti gomina tuntun ni ipinlẹ naa, Ademọla Adeleke sọ ninu ọrọ akọkọ to ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọ nibi iburawọle rẹ atawọn igbesẹ kan to ti gbe.

Lara awọn igbesẹ naa ni yiyi orukọ idanimọ ipinlẹ naa pada si ‘Osun state’ dipo “State of Osun” ti ijọba labẹ iṣakosoẹgbẹ oṣelu APC.

Awọn ohun miran to wa ninu atẹjade ile igbimọ aṣofin Ọṣun

Atẹjade kan ti alaga igbimọ iroyin ati ipolongo nile aṣofin naa, Họnọrebu Kunle Akande fi sita lorukọ awọn ọmọ ile igbimọ naa rọ gomina Adeleke lati yi gbogbo ohun to sọ ati igbesẹ to gbe pada.

Atẹjade naa sọ pe lilo orin ipinlẹ naa, akọmọna ati aworan idanimọ ipinlẹ naa ko ṣa dede waye bi ko ṣe nipa agbekalẹ ofin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa fọwọ si.

Atẹjade naa fi kun un pe lootọ ni ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn da orukọ ipinlẹ naa pada si “Osun state” to wa tẹlẹ lati “State of Osun” ṣugbọn awọn ṣi n reti ki wọn yanju gbogbo eto ipẹjọ to yẹ lori rẹ.

Aworaan atẹjade ti ile aṣofin Ọsun fi sita

Oríṣun àwòrán, Osun Assembly

Lọdun 2011 ni iṣejọba Rauf Arẹgbẹṣọla gẹgẹ bii gomina ni ipinlẹ yi apeja orukọ ipinlẹ naa lede oyinbo kuro ni Osun state si State of Osun

Ofin ile lo gbe orin akọmọna ipinlẹ naa, amin idanimọ ati aṣia ipinlẹ naa kalẹ kii ṣe aṣayan ẹnikẹni.

Ọjọ kejidinlogun oṣu kejila ọdun 2012 ni abadofin orin akọmọna ipinlẹ naa, amin idanimọ ati aṣia ipinlẹ gba ifọwọsi ti ipin gbogbo to wa ni abẹ ofin naa si ti laa kalẹ yekeyek lai si juuju kankan nibẹ.

Nigba wo ni awa aṣofin joko sọrọ lori ọrọ Adeleke? – Họnọrebu Adeyẹmi

Aworan Atejade Honorebi Adeyemi ati aworan Adeyemi funrarẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adewumi Adeyemi

Amọ nigba ti atẹjade yii ṣi n ja ranyinranyin ni ọkan lara awọn aṣofin ile naa to n ṣoju ẹkun Obokun, Họnọrebu Adewumi Adeyẹmi tako atẹjade naa lori pe oun ko mọ igba ti awọn aṣofin joko jiroro lori ọrọ akọsọ Adeleke naa debi ti wọn yoo maa fẹnuko lori ohunkohun.

Họnọrebu Adeyẹmi ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje pe ko si igba kankan ti awọn aṣofin ipinlẹ Ọṣun tii joko jiroro lati gbe awọn koko ti alaga igbimọ iroyin ni ile aṣofin naa fi sita jade.

O wa rọ awọn akẹgbẹ rẹ lati gbaruku ti gomina tuntun naa lati ṣe aṣeyọri nitori ohun to yẹ ko jẹ wọn logun julọ ni igbayegbadun awọn eeyan ipinlẹ naa.