Mọ̀ nípa ìṣèjọba ‘Parliamentary System’ tí àwọn aṣòfin kan ní kí Naijiria padà sí?

Ilé aṣòfin àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, NATIONAL ASSEMBLY

Ikọ̀ ẹlẹ́ni àádọ́rùn-ún nínú àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ń pè fún pípadà sí ètò ìṣèjọba tí àwọn olóyìnbó ń pè ní “parliamentary system of government”.

Parliamentary System of Government ni ètò ìṣèjọba tó jẹ́ pé àwọn aṣòfin ni yóò máa dári ìlú, tí wọ́n yóò sì yan ẹnìkan láàárín láti jẹ́ olóòtú ìjọba gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe ní orílẹ̀-èdè United Kingdom.

Àwọn ọmọ ilé aṣojúṣòfin 90 ló ti buwọ́lu àbá yìí nínú àwọn 360 tí wọ́n wà nílé aṣòfin náà.

Tí wọ́n bá buwọ́lu àbá yìí, èyí túmọ̀ sí pé Nàìjíríà yóò padà sí ètò ìṣèjọba bíi ti ayé Shagari nígbà tí Nàìjíríà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba àwaarawa.

Ní ọdún 2031 ni wọ́n sì ń fojúsùn láti ri pé ètò ìṣèjọba náà bẹ̀rẹ̀.

Àwọn aṣòfin tó gbé àbá yìí kalẹ̀ ni wọ́n pe ara wọn ní Parliamentary Group, ní ètò ìṣèjọba tí Nàìjíríà ń lò báyìí tó jẹ́ pé ààrẹ ló ń darí ìlú kò so èso rere kankan fún Nàìjíríà.

Wọ́n ní owó tí ìjọba ń ná láti fi ṣètò ìjọba ti pọ̀ ju nǹkan tí wọ́n ń ná fún ìdágbàsókè àti ìlọsíwájú orílẹ̀ èdè lọ, tó sì ń fẹ́ àmójútó tó péye.

Wọ́n fi kun pé àwọn fẹ́ kí Nàìjiríà padà sí ètò ìṣèjọba tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yóò ti ní àǹfàní tó pọ̀ lọ́kan ò jọ̀kan àti pé ìfẹ́ àwọn ará ìlú ló máa ń jọba lọ́kàn àwọn olórí lábẹ́ ìṣèjọba yìí.

Aṣòfin Abdussamad Dasuki láti ìpínlẹ̀ Sokoto tó ṣaájú àbá yìí ní àyípadà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láàárín ọdún mẹ́fà tí ètò ìṣèjọba náà fi wáyé.

Ó ní lábẹ́ ìṣèjọba ni gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan, ‘ṣùgbọ́n tí èyí kò rí bẹ̀ẹ́ láti ìgbà tí wọ́n ti gbé ètò ìṣèjọba náà jù sílẹ̀.

Ó fi kun pé ètò ìṣèjọba yìí ni Sardauna Shehu Shagari, fi lélẹ̀ fún Nàìjíríà.

“A fẹ́ ka padà sí ètò ìṣèjọba tó ṣe pé àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní wọ́n máa yan ààrẹ, olóòtú ìjọba àtàwọn mínísítà.

“Ètò ìṣèjọba yìí máa fún àwọn tí wọ́n bá yàn sípò láàyè ní àǹfàní láti ṣe iṣẹ́ ìlú bí ó ṣe tọ́, tí àwọn mínísítà yóò sì ṣe ojúṣe wọn dáadáa nítorí ìlú ló yàn wọ́n kìí ṣe pé ààrẹ ló kàn mú wọn.

“Lára àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tí ètò ìṣèjọba ààrẹ yíyàn mú wá ni pé ó fún ààrẹ ní agbára tó pọ̀ jù, owó ìṣèjọba rẹ̀ sì pọ̀ púpọ̀ jù èyí tó ń ṣàkóbá fún ètò ẹ̀kọ́, ìlera, ohun àmúṣagbára àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”

Abdussamad Dasuqi wá rọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣe àtìlẹyìn tó tọ́ fún àwọn láti lè ri pé ohun tí àwọn ń bèèrè fún wá sí ìmúṣẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, ọmọ ilé aṣojúṣòfin láti ìpínlẹ̀ Kano, Muhammad Bello Shehu Fagge ní lára ìṣòro tí ìṣèjọba lílo ààrẹ mú dání ni níná owó rẹpẹtẹ lórí ìṣèjọba, tó sì ń mú ìdíwọ́ bá àwọn ohun ìdàgbàsókè ìlú tó yẹ kí ìjọba máa náwó lé lórí.

Fagge ní àwọn tí àwọn ti faramọ́ àbá náà ní ilé aṣòfin ti pé 90 báyìí láti ìpínlẹ̀ káàkiri, èyí tó túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ni àwọn ń fẹ́ nǹkankan náà.

Ó ní ọdún 2031 ni àwọn ní èròńgbà pé kí ètò ìṣèjọba náà bẹ̀rẹ̀ tí àwọn bá ti rí àtìlẹyìn ilé aṣòfin àpapọ̀ láti mú àyípadà bá ìwé òfin Nàìjíríà.

Kí ni ètò ìṣèjọba lílo olóòtú ìjọba?

Àwọn aṣòfin ilé aṣojúṣòfin ń fẹ́ kí Nàìjíríà padà sí ètò ìṣèjọba bíi ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì níbi tí olóòtú ìjọba tí wọ́n ń pè ní Prime Minister yóò ti jẹ́ olórí orílẹ̀ èdè.

Ètò ìṣèjọba yìí ni Nàìjíríà ń lò ṣaájú kí a tó gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1960.

Ohun náà sì ni Nàìjíríà lò títí di ọdún 1966 kí àwọn ológun tó fipá gba ìjọba ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kìíní.

Àwọn ológun tó gbàjọba yìí ṣe àkóso Nàìjíríà títí di ọdún 1979 kí ìjọba tó tún padà sọ́wọ́ àwọn alágbádá àmọ́ ètò ìṣèjọba yíyan ààrẹ ni Nàìjíríà padà sí lásìkò náà.

Awọn amuyẹ ti iṣejọba ‘Parliamentary system of government’ ni

Lábẹ́ ètò ìṣèjọba “Parliamentary System of Government”, ọwọ́ àwọn ilé aṣòfin ni àwọn tó wà ní ẹ̀ka aláṣẹ yóò ti máa gbàṣẹ.

Ẹni tó máa ń jẹ́ olórí orílẹ̀ èdè yóò jẹ́ ọmọ ilé aṣòfin. Ètò ìṣèjọba yìí sì máa ń mú ìbáṣepọ̀ tó dára wáyé láàárín àwọn aláṣẹ àtàwọn ọmọ ilé aṣòfin.

Ètò ìṣèjọba yìí máa ń mú kí ìpinnu ìjọba tètè wá sí ìmúṣẹ tó sì máa ń jẹ́ kí ìjọba tètè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ ṣe sí ìlú.

Àmọ́ àwọn onímọ̀ ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìṣèjọba yìí pé kò fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ará ìlú láti yan ẹni yóò jẹ́ olórí wọn nítorí àwọn aṣòfin péréte ló máa ń ṣe èyí àti pé òun ló máa ń fún àwọn ológun ní àǹfàní láti gbà ìjọba bí ó ṣe wáyé lọ́dún 1966.