Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti ilé ìwòsàn aládàni mẹ́fà pa lórí ẹ̀sùn lílo ayédèrú òṣìṣẹ́

Oyo

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government

Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbe ile iwosan mẹfa tipa lori ẹsun pe wọn ko koju oṣuwọn.

Lara awọn ẹsun ti ijọba fi kan awọn ile iwosan naa ni pe wọn n gba awọn oṣiṣẹ ti ko koju oṣuwọn siṣẹ lati maa tọju awọn alaisan.

Kọmiṣọna fun eto iroyin ipinlẹ oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Lasiko to n yẹ awọn ile iwosan kan wo niluu Ibadan, alaga ajọ to n gbogun ti awọn ayederu oṣiṣẹ eto ilera, Dọkita Adekunle Aremu sọ pe awọn n ṣeto naa lati daabo ilera awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

Aremu ni ijọba Oyo ko ni faaye gba ki awọn oṣiṣe ti ko koju oṣuwọn maa tọju awọn alaisan nipinlẹ naa.

O fi kun pe ẹnikẹni to tapa si ofin eto ilera ipinlẹ Oyo yoo foju wina ofin.

O tun rọ awọn araalu lati maa ṣi ijọba ni gbẹrẹ ipakọ ti wọn ba kofiri ayederu oṣiṣẹ eto ilera kankan layika wọn.

O sọ ninu atẹjade naa pe “Afojusun wa ko ṣoro lati damọ, ijọba ipinlẹ Oyo mu eto ilera araalu ni ọkunkundun.

“Ijọba n ri daju pe eto ilera awọn eeyan wa wà lara eyi to dara julọ lasiko yii, ki awọn araalu le wa ni ilera pipe.”

Lara awọn ile iwosan ti ijọba naa gbe tipa ni New Jobi Memorial Hospital; Omolara Clinic & Maternity Home; Amazing Grace Medical Clinic; Emiloju Clinic ati Maternity Centre, Ogbere.

Awọn to ku ni Safeway Clinic, Gbaremu ati Emilagba Clinic ati Maternity Centre, Ibadan.