Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú ǹkan ọmọkùnrin lè gìdìgbà láì rọlẹ̀

Ki lo n jẹ ki nkan ọmọkunrin kere?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii fihan pe eni to ba ni aisan yii ko gbọdọ mu oti tabi fa siga ko ma baa peleke sii.

Arun ẹjẹ ti awọn oloyinbo n pe ni ”Sickle Cell” abi ”Leukemia” jẹ ọkan lara awọn aisan to wọpọ ninu igbeyawo nitori iru ẹjẹ ti awọn mejeeji ni.

Arun ẹjẹ le waye nigba ti awọn ololufẹ to fẹ ara wọn ba ni iru ẹjẹ bii AS ati AS tabi SS ati AS.

Ki lo n jẹ ki nkan ọmọkunrin kere?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arun to lagbara ni arun ẹjẹ, eleyii to ma n fa ipọnju fun awọn eniyan, awọn ẹbi to fi mọ awujọ paapaa.

Iwadii si fihan pe o kere tan, idaji awọn ọmọ ti wọn n bi lorilẹede Naijiria ni ọdọọdun lo ni arun inu ẹjẹ.

Arun ẹjẹ yii tun ma n ṣe akoba fun nkan ọmọkunrin to le mu ki o ma lee ṣe deede pẹlu ololufẹ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ni ọkunrin, arun ẹjẹ yii le mu ki apa wọn ma na si oke, ki ẹjẹ di si apa tabi ki o ma jade.

Ti nkan ọmọkunrin wọn ba na tan, o le ma tete rọle fun ọpọlọpọ wakati, eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni ”Priapism” Pseudomonas aeruginosa.

Ko si bi nkan ọkunrin ṣe le dede tobi si lai ṣe wi pe ẹjẹ n wọ kiri ni agọ ara eniyan bi o ṣe to ati bi o ti yẹ.

Igba kigba ti ara ọkunrin ba le, ni ẹjẹ to wa ni ibi nkan ọmọkunrin rẹ yoo le.

Ti ẹjẹ yii ko ba ṣan bi o ṣe to, ti o lọ di si inu isan kan, eyi le fa ki nkan ọmọkunrin gun sii, ko wu, ki o si le dain-dain.

Ti ara okunrin ba ti walẹ tan ti ẹjẹ yii a ṣan lọ si ibi to yẹ ki nkan ọmọkunrin yoo walẹ.

Amọ ti ọkunrin ba ni arun ẹjẹ, o ṣeeṣe ko ni aisan Priapism yii ti nkan ọmọkunrin rẹ ko ni lọ silẹ bọọrọ.

Eleyii n ṣẹlẹ si ọmọde ati agba to ba ni iṣoro yii, o ṣeeṣe ki wọn maa daku bakan naa.

Iwadii fihan pe aisan yi wọpọ laarin awọn eniyan lati bii ọdun mejila lọ si oke.

Amọ o lee ṣe ẹni ti ko ni arun ẹjẹ naa.

Za a iya sa allura a zuke jinin da ya daskare a gaban namji wanda hakan yana sa a samu sauƙi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Itoju wo lo wa fun aisan ti nkan ọmọkunrin yoo le lai rọlẹ?

Gẹgẹ bi dokita Ibrahim ṣe ṣọ, ko i tii si iwosan to peye fun arun yii lọwọ lọwọ bayii, nitori ọpọlọpọ awọn to ni arun ẹjẹ naa ni kii jade sita fun iranlọwọ.

Amọ, iranwọ wa fun awọn to ni aisan yii fun awọn to ba ṣẹlẹ si ni pajawiri.

”Wọn le fun un ni abẹrẹ ti yoo mu ki ẹjẹ to di naa duro si oju kan lai wọ lọ si ibomiran, ki o si jade ni oju ara.”

”Bakan naa ni wọn lee ṣe iṣẹ abẹ fun un lati mu ki ẹjẹ naa san si ita”.

”Amọ iṣoro to rọmọ iṣẹ abẹ yii ni pe o le fa ki nkan ọmọkunrin ku patapata lai ṣiṣẹ mọ.”

Dokita Ibrahim ni itọju to peye to wa lọwọlọwọ yoo mu ki ọyan ọkunrin ohun bẹrẹ si tobi lasiko to ba n gba itọju, ti yoo si maa yọ omi ọyan bi obinrin.

”Ko si si ẹni to fẹ iru eto ilera bẹẹ laarin awọn ọkunrin, nitori naa ni eto iwosan yii ko ṣe wọpọ laarin awọn ọkunrin.”

”Amọ iroyin rere ni pe iṣẹ nlọ lọwọ lati wa ọna abayọ to peye si ipenija yii laarin awọn ọkunrin.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki ni a le ṣe lati bojuto arun ẹjẹ tabi ki nkan ọmọkunrin ma lọ silẹ lasiko?

Awọn ohun ti ẹni to ba ni aisan yii le ṣe lati dẹkun inira ti o ma n mu ba eniyan ni:

•Mimu omi loore-koore

•Lilọ ṣe igbọnṣẹ loore-koore

•Ṣiṣe ere idaraya yoo gbogunti ẹjẹ didi fun arun ẹjẹ

•Lilo oogun ti yoo mu ki inira naa dikun

•Ko gbọdọ lo omi tutu ju abi yinyin.

•Bakan naa ni ko tẹ ẹ jẹjẹ lasiko ibalopọ abi ko ri wi pe atọ ọmọkunrin, semen jade lasiko.

•Eni to ba ni aisan yii ko gbọdọ mu oti tabi fa siga ko ma ba a peleke si.