Fídíò, Ẹ̀yin obìnrin, ẹ má fọkàn síi pé gbogbo ènìyàn ló máa fi iṣẹ́ ọfíìsì jẹun, ẹ wo àwòkọ́ṣe mi – Adekemi Olugbade, Duration 5,02

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Kò sóhun tó leè yà mí ya iṣẹ́ mi, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dé góńgó”.

“O ti n lọ si ọdun mẹfa ti mo ti bẹrẹ iṣẹ ikoko mimọ nigba ti mo wa ni ile iwe girama.”

Adekemi Olugbade ni iṣẹ agbara ni iṣẹ amọ lati fi mọ koko to si jẹ pe ipenija rẹ pọ gidi gan.

“Mo mọ pe awọn ọkunrin lo wọpọ nidi iṣẹ yii tori iṣẹ to le ni, igba mii a maa ṣe koko to pọ rẹpẹtẹ. Ka fẹ ko amọ, ka fẹ wuu, ka fẹ ṣẹẹ bi ogi tori ati yọ idọti to wa nibẹ”.

Adekemi Amọkoko

Agunbanirọ ni Adekemi lọwọlọwọ ṣugbọn o kọ lati dara le wiwa iṣẹ ijọba kaakiri.

Adekemi yan lati diidi lọ si ile iwe giga fasiti lati lọ kọ iṣẹ amọkoko lẹyin to ti bẹrẹ rẹ nileewe girama to si ti rii pe ifẹ oun na mọ iṣẹ naa. O ni oun tun lọ kọ ẹkọ naa sii gidi gan ni ilu Ikire.

Adekemi Amọkoko

Oríṣun àwòrán, cherry_kemi

Adekemi ni oun ko lee fẹ ẹni ti ko ba ti le fẹ oun pẹlu iṣẹ ti oun yan laayo.

“Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé”.

Amọ lorii gbogbo ipenija rẹ, Adekemi ni oun kii jẹ ko da oun laamu, “bi koko ba fọ, ao tun un mọ ni o”.

Ifẹ ati igboya yii lo mu ki awọn iṣẹ ara ọtọ to rẹwa ti eeyan ko ni lee koju kuro afi ki eeyan raa lo n ti ọwọ Adekemi jade.