Mo kábàmọ̀ pé mo ṣe ìgbéyàwó – Ini Edo

Aworan Ini Edo

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja osere tiata, Iniobong Edo ni o ti tẹnu bọrọ lori bi igbeyawo rẹ se fori sọnpọn, to si ni oun kabamọ pe oun se igbeyawo ọhun.

Ini Edo ninu ifọrọwerọ kan to se pẹlu Chude Jideonwo, ni o seese ki oun tun ni oun fẹ se igbeyawo miran ti oun ba pada ẹni to kajuẹ lati jẹ ade ori fun un.

Lọjọ kejidinlọgbọn, ọdun 2008 ni oṣere naa se igbeyawo pẹlu Philip Ehiagwina sugbọn ti igbeyawo naa forisọnpọn lẹyin ọdun marun un, ti wọn si tuka lọdun 2013.

Ini Edo ni awọn mọlẹbi oun lo ti oun lọ se igbayawo nigba naa sugbọn oun yoo tun ro ti oun ba pada ẹni to jẹ ti toun.

“Mo kabamọ ipinnu mi lati se igbayawo nitori ko ki n se igbesẹ to yẹ ki n gbe niyẹn.”

Lọdun 2021, Ini Edo bi ọmọbinrin kan lẹyin to wa ẹni ti yoo ba gbe oyun naa, eyi ti oloyinbo n pe ni Surrogacy.

“Mo pinnu lati wa ẹni ti yoo ba mi gbe oyun nitori bi oyun se n bajẹ mọ mi lara.”

“N ko ni ọkọ, ṣugbọn mo fẹ ni ọmọ laye, boya mo ni ọkọ tabi n ko ni ọkọ. Mo wa rọ pe kini ọna abayọ fun mi, nitori mo fẹ ko jẹ ọmọ mi gan-an-gan.

“Wọn wa gba ẹyin mi lati fi se isẹ abẹ ọhun.”