NÍ YÀJÓYÀJÓ Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà 126 mìíràn tún padà sílé láti Sudan nítorí ogun

Copyright: Reuters

Kaakiri
agbaye ni wọn ti n fi ikini ibanikẹ̀dun ransẹ si awọn mọlẹbi eniyan marun
un to ku ninu ọkọ oju omi Titan laipẹ yii.

Awọn
marun un naa ni wọn di awati ninu ọkọ oju omi ni agbami Atlantic Ocean
lorilẹede Amẹrika.

Lati
Ọjọ Aiku ti ọkọ naa ti gbera lati lọ si isalẹ omi nibi ti ọkọ oju omi
Titanic wọlẹ si ni ọdun 1912 ni wọn ti gburo wọn mọ.

Awọn ti wọn wa ninu ọkọ submarine naa ni arakunrin Stockton
Rush, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgọta to si tun jẹ adari ileeṣẹ OceanGate, oniṣowo
Ilẹ Gẹẹsi to tun jẹ ọmọ ilẹ Pakistan, Shahzada Dawood, ati ọmọ rẹ Suleman, ati
oniṣowo Ilẹ Gẹẹsi miran, Hamish.

Copyright: Getty Images

Awọn marun
un ọhun lọ fun igbafẹ ni lati lọ wo Titanic ọhun, amọ ọkọ wọn poora ti
wọn si bẹrẹ si ni wa wọn fun ọjọ marun un.

Ninu
atẹjade ti orilẹede Amẹrika fi lede ni wọn ti ni ko pẹ ti ọkọ oju omi
naa gbera ti o gbina ninu okun naa.

Ileesẹ
aarẹ Ilẹ Amerika, White House fi atẹjisẹ ransẹ si awọn mọlẹbi oloogbe
naa, ti wọn si ba wọn kẹdun awọn mọlẹbi wọn to doloogbe.

Bakan naa ni
ikọ ẹsọ alaabo omi ni Canada naa ni awọn ri afọku ibugbamu ni ọna marun
un ti ko ju iwọ ẹsẹ 1,600 si Titanic ti wọn fẹ lọ wo ni isalẹ omi.

Awọn
mọlẹbi awọn marun un to doloogbe naa fi atẹjade sita pe kaakiri gbogbo
agbaye ni awọn eniyan ti n fi ibanikẹdun ranṣẹ si wọn.