April Fool kọ́, ìjọba tí buwọ́lu òfin tó faramọ igbó fífà bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kíní oṣù Kẹrin

Aworan awọn to n fa igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Awọn eeyan orileede Germany kan wa to ṣe pe lẹyin ti wọn ba pari iṣẹ oojọ wọn, ọti ni wọn nifẹ si ni mimu.Awa kan ṣaa fẹ maa fa igbo ni tiwa ni.’’

Gbolohun ree lẹnu Marcel Ritschel to n dawọ idunnu lẹyin ti orileede Germany tawọn eeyan mọ fun ọti mimu ti ṣe faramọ igbo fifa.

Bẹrẹ lati ọjọ Kini oṣu Kẹrin, ijọba ti faaye gba igbo fifa fun araalu amọ igbalaaye yi wa pẹlu alaye.

Amọ awọn agbofinro n ke gbajare pe ewu nla n bẹ loko longẹ pẹlu igbesẹ yii.

Ijọba kede iyipada ofin lori ọrọ yii.eyi ti yoo gberasọ layajọ April Fool lootọ ṣugbọn awada kọ ni ọrọ to wa nilẹ yii.

Nibi tawọn eeyan ti kora jọ ni Neustadt, agbegbe Dresden ti faaji a ti maa sẹlẹ laarin gbungbun ilu naa ni a ti ṣalabape Marcel Ritschel.

Ni aaye yi, niṣe lawọn eeyan n fa igbo ni ita gbangba ṣaaju ki ijọba to kede didẹkun ofin to de ma fagbo toi wa nilẹ tẹlẹ.

Lara awijare to mu ki wọn faaye gba igbo fifa naa re-aimọye lo ti n fa igbo tẹlẹ ki ijọba to ni awọn faaye gba.

Wọn tun sọ pe yoo dẹkun awọn to n ta igbo lọna ẹburu nigba ti igbalaye ba ti wa lati ta nita gbangba.

Ohun tawọn to n ja fun fifa igbo ni ita gbangba sọ ree gẹgẹ bi awijare ti wọn.

Aworan ẹni to n fa igbo

Oríṣun àwòrán, AFP CONTRIBUTOR

Ki ni ofin tuntun naa sọ?

Bẹrẹ lati Ọjọ Kini oṣu Kẹrin

  • Awọn ti ọjọ ori wọn ba kọja ọdun mẹrindinlogun le ni igbo ti iwọn rẹ jẹ 25kg nita gbangba ti ko si ni tako ofin
  • Awọn agbalagba le gbin igi igbo mẹta ni idile kọokan
  • Ṣugbọn awọn eeyan ko ni lanfaani lati fa igbo layika ile ẹkọ, ibudo idaraya tabi ibi tawọn to n fẹsẹ rin loju popo ba wa laarin ago meje owurọ si ago mẹjọ alẹ.

Bẹrẹ lati ọjọ Kini oṣu Keje:

  • Aaye wa fun idasilẹ ẹgbẹ onifaaji awọn to n gbin igbo, ti ọmọ ẹgbẹ ko si gbọdọ ju ẹẹdẹgbẹta lọ
  • Ọjọ ori awọn ọmọ ẹgbẹ gbọdọ kọja ọdun mejidinlogun, ti wọn si gbọdọ jẹ olugbe Germany
  • Awọn ẹgbẹ yi lanfaani lati gbin, ki wọn si ṣalabapin igbo yii ṣugbọn wọn ko gbọdọ ṣe bẹẹ lọna ati fi pa owo
  • Ko saaye fun wọn lati fa igbo yii ni aaye ti wọn ti n gbin igbo.

Ọ́pọ̀ ọdọ ti ọjọ ori rẹ̀ ko tii to ọdun mejidinlogun ni yoo maa wa ọna ẹburu lati ra igbo.

Ọjọ ti pẹ ti awọn to n mu igbo ti fẹ ki wọn ṣọ mimu ati tita rẹ di ohun ti ofin faaye gba.

Bawọn kan ṣe n yayọ ofin tuntun yii, ni awọn to tako bi Ọjọgbọn Ray Walley ṣe sọ pe ilana tuntun yi yoo ṣe akoba fun ilera, ti yoo si tun mu alekun ba iye awọn to n fa igbo.

O ni pẹlu pe awọn ti ọjọ ori won ko to ọdun mejidinlogun ko le jẹ anfaani ofin yi, pupọ awọn ọdọ ni yoo maa wa ọna ẹburu lati ra igbo.

Orileede Germany wa lara awọn orileede to ti n ṣe iye meji lori ọrọ fifi ofin de igbo fifa nita gbangba.

Ni orileede Canada, o ti ṣe diẹ ti igbo mimu ati tita lai bẹru agbofinro ti di gbẹfẹ.

Orilẹede Canada si ni orilẹede keji to tu okun ofin lọrun Kukuye lẹyin ti orilẹ-ede Uruguay ti se bẹẹ.