Mi ò sọ pé àwọn tó ń pè fún Yorùbá Nation kò yàtọ̀ sí Boko Haram o- Gbajabiamila ṣàlàyé

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Femi Gbabiamila

Adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, Femi Gbajabiamila ti ṣalaye pe oun ko sọ pe awọn to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation ko yatọ si ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram.

Ni Ọjọru ni iroyin gbee Gbajabiamila sọ pe ẹgbẹ IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra ati Yoruba Nation ko yatọ si Boko Haram.

Amọ, oludamọran adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin lori ọrọ iroyin, Lanre Lasisi sọ ninu atẹjade to fi sita pe ọrọ ko ri bẹẹ.

Ọgbẹni Lasisi ṣalaye pe Gbajabiamila ko darukọ ẹgbẹ ajijagbara kankan ninu ọrọ rẹ.

”Oun ti adari ile igbọmi aṣoju-ṣofin sọ pe awọn ọdaran kan n lo iwọde tawọn kan fi n pe fun iyapa kuro lara Naijiria lati da rogbodiyan silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọpọ awọn ọdaran to n pe ara wọn ni ajijagbara lapa Guusu Naijiria papaa julọ nilẹ Igbo ati Yoruba ti n da ilu ru.

Bakan naa ni wọn gba ẹmi awọn alaiṣẹ ti wọn si tun ṣe akoba fun ọrọ aje orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn o ṣetan lati jiroro pẹlu ijọba lori ohun to n dun wọ, nitori naa, wọn o yatọ si Boko Haram ati ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP.

Ko si ohun to jọọ pe Gbajabiamila darukọ ẹgbẹ kankan ninu ọrọ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ohun to sọ naa ni pe awọn ọdaran kan n fi ijijagbara boju lati ṣe iṣẹ ibi.

Gbajabiamila ko tabuku ijijagbara, bẹẹ ni ko si sọ pe awọn to n jija gbara ko yatọ si Boko Haram,” Lasisi lo sọ bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ