Ọkùnrin tó lẹ ”Super Glue” mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ”condom” ti dèrò ọ̀run

Ọ̀kùnrin àti obìnrin

Kayeefi ni ọrọ yii jẹ fun ọpọlọpọ eeyan to ti gbọ nipa rẹ o.

Ọkunrin kan lo dero ọrun lẹyin to lẹ ”super glue” oko rẹ nigba to gbagbe rọba idaabobo ṣaaju ibalopọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ ti jẹ Ọlọrun nipe.

Salman Mirza, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ni iroyin sọ pe o lẹ ”super glue” mọ nkan ọmọkunrin rẹ lati le dena oyun nigba ti o fẹ ni ablopọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ nile itura kan niluu Gujarat lorilẹede India.

Oun ati ololufẹ rẹ ni a gbọ pe wọn lo oogun oloro ki wọn ba le lagbara fun ibalopọ gbankọgbi ti wọn fẹ ṣe nile itura.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Mirza ni wọn ba ni ita ile itura naa ni ọjọ keji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọga ọlọpaa niluu Ahmedabad ṣalaye pe awọn mejeeji tun fin awọn oogun oloro mii si imu ki wọn to bẹrẹ ibalopọ wọn.

Ọpọ eeyan ni adugbo ni wọn jẹri pe awọn mejeeji maa n ṣaaba lo oogun oloro papọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigba ti wọn ri Mirza nibi to wa ni ita ni wọn gbe e digba digba lọ si ile ile iwosan.

Amọ, ọwọ ti bọ sori, ile iwosan yii naa ni o ti dagbere faye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ẹbi Mirza pe fun iwadii lori ohun to pa ọmọ wọn.

Ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to pa ọmọkunrin yii gan an, o ni esi maa to jade laipẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ