”APC yóò fún Goodluck Jonathan ní ànfàní láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 tó bá darapọ̀ mọ́ wa”

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Goodluck Jonathan

A ṣetan lati tẹwọ gba aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Goodluck Jonathan ni APC to ba fẹ darapọ mọ wa.

Akọwe agba amuṣẹya APC, John Akpanudoedehe ni gbogbo ẹtọ to tọ si ọmọ ẹgbẹ tuntun ni Jonathan yoo j’anfaani rẹ to ba le darapọ mọ APC.

Akpanudoedehe ṣalaye lori ileeṣẹ amohunmaworan Channels pe ẹgbẹ yoo fun Jonathan lanfaani lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023 to ba le darapọ mọ APC.

Amọ, o ṣalaye pe Jonathan yoo lanfaani lati dije ninu ibo abẹle pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ mii naa to fẹ dupo aarẹ lọdun 2023.

Akpanudoedehe ni lai ṣer ani ani ẹgbẹ APC yoo tun gbilẹ si bi Jonathan ba le darapọ mọ ẹgbẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣé lóòtọ́ ni Goodluck Jonathan ti fi PDP sílẹ̀ dárapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú míì? Ohun táa mọ̀ rèé

Ojoojumọ ni gbọyii- sọyii nipa kikuro lẹgbẹ oselu PPD ààrẹ ana ni Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan n gbooro síi jakejado orilẹede. Amọ njẹ ootọ ni?

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti sọrọ pe àwọn kò tii gbọ ọrọ náà latenu ọlọrọ tii ṣe olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri.

PDP sọ fún BBC ni san Ọjọru pe ààrẹ ana, Goodluck Jonathan ko ti bun awọn gbọ lori boya o ni ààtò miiran lati kuro ninu ẹgbẹ.

Ọgbẹni Jonathan lo jẹ ààrẹ Naijiria lati oṣu karun ọdun 2010 titi di oṣu karun ọdun 2015 labẹ àsìá ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bi iroyin naa se wa ni di eyi ti wọn ni gba bi ẹni n gba igba ọtí lo mú ki ẹgbẹ alatako ni Naijiria ìyẹn PDP tan imọlẹ sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

A kò tii ri aridaju kankan bẹẹ sì ni awuyewuye hun ni gbilẹ ṣii lati alẹ ana.

Akọwe ẹgbẹ PDP, Kola Ologbondiyan ṣàlàyé fún BBC l’owurọ Ọjọru pe awọn o gbọ ohun tó jọ bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹgbẹ to jẹ ẹgbẹ alatako lasiko ìṣèjọba Goodluck, APC náà bọlé lọdun 2015 to ni dije fún atunyan ti ààrẹ to wà lórí aleefa bayii, Buhari si jáwé olubori.

Eyi lo sọ Goodluck Jonathan di ààrẹ akọkọ to wà lórí oye ti wọn gbọn yọ pẹlu ibo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ, Ọga Jonathan pe Ààrẹ Buhari lati kii ku oriire koda ki àjọ INEC to kede esi. Eyi mú kí ọpọ ọmọ Naijiria nile ati lẹyìn odi ríi gẹgẹ bí “Akíkanjú alafia”.

Ẹgbẹ oṣelu PDP gbagbọ pe ihuwasi Goodluck yii lo tun mú ọkàn balẹ niluu tó si bori gbogbo wahala tabi itajesile ti orilẹede yìí ko ba foju ri.

Nibo ni Jonathan wa bayii?

Lati ọdún 2015 to ti fìdí rẹmi nipo ààrẹ, Ọga Jonathan ti sin orilẹede yìí ati ilẹ Afirika loniruuru ọna fún iṣẹ wiwa alaafia.

Eyi to ṣe laipẹ yìí ni iṣẹlẹ ipaniyan to waye ni Guinea nibi to ti ni ṣiṣẹ gẹgẹ bii olulaja fún àjọ ọrẹd’ẹgbẹ ECOWAS.

Lọwọlọwọ, o n ba awọn ologun f’ọrọ jomitoro ọrọ lori ọna abayọ to dara ju fun ẹkun naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ