Ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù le tún peléke síi nítorí làásìgbò Russia àti Ukraine

Ọ̀pá epo

Bí ẹlẹ́sẹ̀ bá ń jìyà ó ṣeéṣe kí olódodo máa pín nínú rẹ̀.

Ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù tó ti ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra láti bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn ló ṣeéṣe kó tún tẹ̀síwájú nítorí làásìgbò orílẹ̀ èdè Russia àti Ukraine.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo bẹntiróòlù tó ń wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló jẹ́ pé láti àwọn ẹkùn orílẹ̀ èdè tó ń kọjú ogun síra wọn ló ti ń wá tí ìdíwọ́ sì le wà fún wọn lọ́wọ́ yìí nítorí ìkọlù tí Russia ń gbé kojú Ukraine.

Bákan náà ló ṣeéṣe kí ìdíwọ́ tún wà fún àwọn ọlọ́jà tó ń gbé epo bẹntiróòlù wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bí àdínkù ṣe ti bá àwọn ọkọ̀ tó ń gbé epo rọ̀bì láti àjọ NNPC lọ sí ilẹ̀ òkèrè.

Àjọ NNPC ló máa ń gbé epo bẹntiróòlù wọ Nàìjíríà nípasẹ̀ àwọn ọlọ́jà tàbí àwọn kọngilá lábẹ́ ètò DSDP.

Lábẹ́ ètò yìí àjọ NNPC yóò fún kọngílá ní epo rọ̀bì tí wọn yóò fi san iye epo bẹntiróòlù tó bá jẹ́ padà fún àjọ NNPC.

Ọ̀pá epo

Oríṣun àwòrán, NNPC

Báwo ní ìjà Russia àti Ukraine ṣe lè mú ọ̀wọ́n gógó bẹntiróòlù bá Nàìjíríà?

Yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè ìwọ̀ oòrùn Yúròpù bíi US, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà máa ń fọ epo rọ̀bì nì àwọn ìlà oòrùn Yúròpù náà.

Èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeéṣe kí àwọn epo bẹntiróòlù Nàìjíríà tó há sí àwọn ilé ìfọpo Russia àti Ukraine kí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì ni kò ní lè jáde lásìkò tó yẹ báyìí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bákan náà ni owó tí wọ́n fi ń gbé epo rọ̀bì láti US lọ sí UK àti àwọn ẹkùn Asia ló ti gbowó lórí láti mílíọ̀nù mẹ́rin dọ́là àgbá méjì lọ mílíọ̀nù méje dọ́là lọ́jọ́ Ẹti tó kọjá.

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbé epo pàápàá tí ń sá fún láti lọ gbé epo ní Russia nítorí yí àwọn àwọn ọmọ ogun Russia ti ṣe ìkọlù sí àwọn ọkọ̀ ojú omi mẹ́ta tó gbé epo rọ̀bì mẹ́ta lẹ́nu ìgbà tí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láà’srín òhun àti Ukraine.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn ilé iṣẹ́ agbépo ń kọminú lórí owó tí wọ́n fi ń gbé ọjà:

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún àwọn ọmọ bíbí Nàìjíríà tó ní ọkọ̀ ojú omi, Aminu Umar ní ó burú jáì láti gbé ọjà láàárín Russia sí Ukraine nítorí tí wọ́n ti kéde ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi tógun ti ń wáyé.

Umar ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ tó ń gbépo láàárín Black sea àti Mediterranean ni wọn kò ní lè gbé epo lọ sí Yúròpù, Amẹ́ríkà àti àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ó ní èyí yóò ṣe àkóbá fún bí ọkọ̀ ojú omi tó ń gbé epo bẹntiróòlù ṣe le wọ Nàìjíríà.

Umar ní ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tún ti fa kí àlékún owó tí àwọn ń fi ń gbé ọjà lórí táńkà kan láti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là di ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n dọ́là lọ́jọ́ kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Emmanuel Ilori tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọjà kíkó wọlé láti ilẹ̀ òkèrè ní àkókó yìí jẹ́ àsìkò tó yẹ ki Nàìjíríà jí gìrì sí ojúṣe láti dá dúró, kí wọ́n wá ojútùú sí àwọn ilé ìfọpo tí gbogbo rẹ̀ ti dẹnu kọlẹ̀.