Makinde, ìràwọ̀ igbákejì rẹ lò ń lò, òun gan ló yẹ kó jẹ́ gómìnà dípò rẹ – Igun PDP

Igbakeji gomina, Aderemi Olaniyan ati gomina Seyi makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Eku ko ke bi eku mọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ bayii pẹlu bi awọn adiyẹ ẹgbẹ naa se ti n jẹ ifun ara wọn ni igbaradi fun idibo apapọ ọdun 2023.

Ni ọjọ Aje lawọn agbaagba kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa lati ijọba ibilẹ gbogbo to wa ni ipinlẹ Ọyọ, ko ara wọn jọ ni ilu Ibadan nibi ti wọn ti pariwo sita pe, awọn ko fẹ Seyi Makinde gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu awọn mọ, nitori naa, ko yara kọwe fipo silẹ lẹgbẹ PDP lo tọ.

Nigba ti BBC News Yoruba kan si igun ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọyọ naa, wọn ni lootọ lawọn sọ bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A ko ri nnkan jẹ labẹ Makinde, la se fẹ́ẹ le:

Njẹ ki ni idi eyi, ṣe wọn ni ọmọ ẹni kii saa sedi bẹbẹrẹ, ka lọ ree fi ilẹkẹ sidi ọmọ ọlọmọ; awọn agbagba ẹgbẹ to n fi ẹhonu han naa ṣalaye pe “awọn to n ṣiṣẹ ko ri nnkan jẹ” labẹ iṣejọba Gomina Makinde, lawọn ṣe woye pe ko kuku maa lọ, awọn ko fẹ mọ.

Bakan naa ni wọn fi kun pe, ara aiṣedede rẹ ni ko jẹ ki aarin oun ati igbakeji re o gun rege

O ni igbakeji rẹ gan lo yẹ ko dije gomina, ki wọn to gbe fun Makinde.

“A difa ifa ko mu. Irawọ onirawọ lo n lo. Ẹ sọ fun ko wa sọ ibi ti wọn ti mu u.”

Asiwi ni pe oloselu nikan ni ko fẹran Makinde – Nureni Akanbi

Alaaji Nureni Akanbi to ba BBC Yoruba sọrọ lorukọ awọn agbagba ẹgbẹ to n fapa janu naa ṣalaye pe, aṣiwi ọrọ lawọn to n sọ pe awọn oloṣelu ni ko fẹran Gomina Makinde, ṣugbọn araalu fẹ.

O ni to ba jẹ pe lootọ lawọn araalu fẹran rẹ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, o yẹ ko wọle ni igba mẹta ọtọtọ to gbe apoti ibo ṣaaju ọdun 2019.

“Araalu to ba n fẹ yoo sọ. Awọn wo laraalu? Ṣe wọn ṣe araalu ju awa lọ ni?”

O ni lara awọn ẹsun ti wọn n fi kan Gomina Makinde ni pe “ko ṣe dede saraalu, ko ṣe dede si ẹgbẹ. Awọn ajeji lo n janfani iṣẹ to n ko wa. Iṣẹ ijoba ti wọn n ṣe ọmọ ipinlẹ Ọyọ wo lo gbe fun?”

Alhaji Akanbi fi kun pe nigba ti wọn ba dibo, yo lee sọ boya araalu fẹran rẹ tabi rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alawada kẹrikẹri ni awọn to ni ki Makinde fi ẹgbẹ silẹ – PDP

Ṣe wọn ni agbẹjọ ẹnikan da, agba osika ni. Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ naa sọrọ, wọn ni alawada lawọn agba ẹgbẹ to korajọ pẹlu ẹhonu naa.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Akeem Ọlatunji ṣalaye fun BBC Yoruba pe ohun ti awọn agbaagba to korajọ naa ṣe lodi si ofin ẹgbẹ oṣelu PDP.

O ni ko si iṣejọba tiwantiwa ti awọn igun perete ti n la le igun to pọju lọwọ.

“Igun to wa ni PDP nipinlẹ Ọyọ le ni igba, ti ẹyọ kan ninu igba yii ba wa sọ pe awọn ko si lẹyin gomina Makinde, o yẹ ka fura si wọn.”

Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ naa ni awọn perete kan lo kan kora wọn jọ lati lọ ṣe awada kẹrikẹri.

O ni ẹgbẹ oṣelu PDP yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lori wọn laipẹ nitoripe awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu PDP ti ri aridaju pe, awọn kan lẹgbẹ APC lo n lulu fun iromi wọn.

O fi kun pe nitori idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP to n bọ lọna, ni wọn se n gbe igbesẹ lati da wahala silẹ laarin ẹgbẹ.

Amin iyasọtọ kan

Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó – Igun PDP Oyo

Awọn eekan PDP ni Oyo

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Awọn igun ti inu n bi ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo ti ni ki gomina Seyi Makinde kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ki alaafia le jọba.

Awọn ogbontagiri oloselu ni ẹgbẹ oṣelu PDP fi ipe naa ranṣẹ lasiko ipade gbogboogbo ti wọn ṣe ni ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn n fi apa janu lati ijọba ipinlẹ mẹtalelọgbọn ni ipinlẹ Oyo, ni wọn parapọ si ibi ipade gbogboogbo naa saaju idibo abẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ tirẹ, adari awọn ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ ni Ile Igbimọ Aṣofin Naijiria kekere tẹlẹ, Milikat Akande Adeola ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Kẹsan ni idibo abẹle naa yoo waye.

Wọn parọwa si awọn eniyan lati mase ja lasiko idibo naa, amọ ki wọn ya aworan pẹlu fidio gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ lasiko idibo abẹle naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ogbontagiri ni ẹgbẹ oṣelu PDP miran, Nureni Akanbi ni awọn ko le e gba laelae ki ọjọ ọla awọn wa lọwọ iru eniyan bi gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde.

Bakan naa ni awọn ti wọn fi apa janu naa ni awọn yoo ri daju pe gomina Seyi Makinde ko pada si ipo gomina ipinlẹ Oyo ni ọdun 2023, to ba n wa saa keji.

Koko ẹsẹ meje tawon ogbontagiri oṣelu PDP l‘Oyo fi tako Makinde?

  • Awọn igun ti wọn pe fun iyokuro Seyi Makinde ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni gomina naa ko naani gbogbo awọn to ṣiṣẹ fun un bi o ṣe di gomina nipinlẹ Oyo
  • Wọn ni gbogbo ileri ti Seyi Makinde ṣe fun wọn lasiko idibo ati lẹyin idibo ni ko si eyi to muṣẹ nibe nitori gbogbo awọn to ṣiṣẹ nigba naa ni gomina danu, to si fi awọn eniyan to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa si ipo
  • Awọn ogbontagiri ni ẹgbẹ oṣelu naa ni gomina Makinde ati awọn alatilẹyin rẹ ti gba ẹgbẹ PDP nipinlẹ Oyo mọ awọn to laagun ṣiṣẹ lasiko idibo ọdun 2019 lọwọ
  • Wọn ni gomina Makinde n kọ orukọ awọn eniyan tirẹ to fẹ ko wa ni ipo olori ni idibo abẹlẹ ẹgbẹ naa ni awọn wọọdu
  • Awọn wọnyii ni wọn gbagbọ wi pe ko lagbara, ti wọn ko si ni awọn alatilẹyin yato si gomina ipinlẹ Oyo ti wọn n tẹlẹ nikan
  • Wọn ni imọtara ẹni nikan ti gomina Makinde fi n ṣe ijọba ko jẹ ki awọn oloṣelu to fi mọ awọn aṣofin ipinlẹ lati ri iṣẹ akanṣe fun awọn eniyan wọn
  • Awọn to n fapa janu naa ni gomina kọ lati gba imọran awọn lati jẹ ki awọn eniyan dibo fun ẹni ti wọn fẹ, ki Seyi Makinde ma gbe ẹnikẹni le wọn lori.

Laipẹ yii ni oludije si ipo aarẹ ni ọdun 2019, Atiku Abubakar, to fi mọ Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba ni Naijiria, Bukola Saraki ti gbiyanju lati pari aawọ laarin gomina Seyi Makinde ati awọn to n fi apa janu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Oyo naa, amọ pabo lo jasi.