Ilé wó lé èmí, àya àtí ọmọ márùn ún lórí, ẹ̀mí ìyá mí lọ sí – Olùgbé ilé tó dàwó ní Akure

Akure

Ẹmi eniyan kan lọ, ti mọlẹbi si farapa ninu iṣẹlẹ ile alaja kan to wo ni agbegbe Fanibi ni ilu Akure, ni ipinlẹ Ondo.

Awọn mọlẹbi ti wọn fi ara kasa iṣẹlẹ naa ni ẹmi iya agba awọn gan lọ si iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni awọn ọmọ marun un to wa ninu ile nigba ti iṣẹlẹ naa waye lo farapa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olugbe ile naa ti o padanu iya rẹ, Pasitọ Solomon Benson ni inu ibanujẹ ọkan ni oun wa lọwọlọwọ,ti ko i tii si iranwọ lati ọdọ ẹnikẹni.

”A n sun lọwọ ni afẹmọjumọ ni nkan bi aago mẹta oru ni ile naa dede dawo, ti ohun gbogbo si ṣokunkun.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Gbogbo dukia ti mo ni lo ba ile to dawo naa lọ, ti iya mi si tun gbẹmi mi.”

”Ohun to fa ti ile naa fi wo ni pe awọn onile naa fẹ sọ ile yara meji di yara marun un lẹkan naa”

”Mo kesi ọkan lara awọn to ni ile naa, amọ nitori ile wọn ko gun, ko si nkan ti wọn ṣe si ile alaja ti ọkan lara awọn onile naa fẹ kọ si inu ile ọhun.”

”Wẹrẹ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni mo ti pe ọlọpaa nitori ọmọ to wa ni ẹgbẹ mi ni mo kọkọ ju si ita ko ma ba a ku.”

”Lẹyin naa ni mo doola ẹmi iyawo mi, ti awọn ọmọ si ti ha si ibẹ, amọ awọn araalu dide si wa, ti wọn si ranwalọwọ”

”Kiakia naa ni mo gbe ọmọbinrin mi ti ”block” wo le ori rẹ lọ si ileewosan, ti wọn si doola ẹmi rẹ amọ wọn ni ki a gbe lọ si ileewosan ti wọn yoo ti ya aworan ọpọlọ rẹ lati mọ wi pe o wa ni alaafia.”

Akure

”Ko si aṣ, ko si ile ti awọn ẹbi yii yoo ma a gbe, ijọba ẹ ran wọn lọwọ”

Ọkan lara awọn ara adugbo ti iṣẹlẹ naa sọju rẹ rọ ijọba lati saanu awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa, ki wọn si ran wọn lọwọ.

Awọn ara adugbo ni wọn nilo ile ti wọn yoo gbe, nitori aṣo ati dukia pẹlu ohun gbogbo ti wọn ni lo lọ si ijamba naa.

Akure

Wọn wa parọwa si ijọba lati ri pe awọn eniyan gba awọn iwe to yẹ nipa ile kikọ ati wi pe ki awọn eniyan ma a kọ ile daradara.

Amọ lara awọn ara adugbo to sọrọ naa ni iya ati iṣẹ to n ba awọn eniyan finra lo mu ki wọn lo gbe iru ile ti ko bun iyin kun eniyan rara.