Ìròyìn ayọ̀, Iyabo Oko kúrò nílé ìwòsàn, ó ń sọ̀rọ̀ fatafata àmọ́…

Iyabo Oko

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Iroyin ayọ to n jade sigboro bayii ni pe gbajumọ osere tiata nni, Iyabo Oko to n saisan ti ri iwosan gba.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni osere tiata kan, Foluke Daramola kede loju opo Instagram rẹ pe ojojo n se Iyabo Oko, ti ara rẹ ko si le.

Ninu fidio naa si ni Foluke ati ọmọ Iyabo Oko ti n bẹbẹ fun iranwọ owo fun osere tiata naa, ki ara rẹ le ya pada.

Amọ ninu fidio miran to gbe soju opo Instagram rẹ lọjọ Isegun, ni Foluke Daramola ti sisọ loju rẹ pe Ọlọrun ti gbọ adura awọn lori Iyabo Oko.

Fidio naa lo kede pe ile iwosan ti ni ki Iyabo Oko maa lọ sile ams o nilo dokita ti yoo maa ba na isan ati egungun rẹ.

Foluke Daramola ni “Dokita ti ni ka maa gbe mama lọ sile amọ wọn nilo lati maa se Physio, ki isan ati egungun wọn le na.

A nilo eeyan to le maa ba wa se ni owo ti ko wọn ju, ti yoo ma ba wa tọju wọn.

Ẹnikẹni to ba ni oju aanu, ti owo rẹ ko wọn ju, ẹ wa ba wa se.”

Lẹyin naa la ri ti Iyabo Oko n sọrọ, to si n fi osere tiata kan, Aderupoko, toun naa wa nile iwosan pẹlu Foluke se yẹyẹ pe o fẹran obinrin pupọ.

Iyabo Oko tun wa dupẹ pupọ lọwọ awọn to se iranwọ owo fun lati se itọju rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

  • Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
  • Ọlópàá ní lóòótọ́ ní ọtá ìbọn bá Jumoke Oyeleke ní Ojota ṣùgbọ́n…
  • Àṣà ìdaranjẹ̀ ti di èèwọ̀ ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà nílẹ̀ Yorùbá
  • Makinde, ìràwọ̀ igbákejì rẹ lò ń lò, òun gan ló yẹ kó jẹ́ gómìnà dípò rẹ – Igun PDP
  • Ilé wó lé èmí, àya àtí ọmọ márùn ún lórí, ẹ̀mí ìyá mí lọ sí – Olùgbé ilé tó dàwó ní Akure
  • Bí Yoruba kò bá yíwà padà, ẹkùn àríwá ní ipò ààrẹ yóò máa lọ – Oluwo
  • “Tí Sunday Igboho, Nnamdi Kanu bá bọ́ sínú APC, wọn yóò gbá ìtúsílẹ̀”
  • Ète ìdìtẹ̀ gbàjọba forí sánpọ́n ní Sudan
  • Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó – Igun PDP Oyo
  • Aisha Yesufu kó ọ̀rọ̀ Ooni dànù, ó ní ohun tó kàn kọ́ ni Ọòni fẹ́ lọ ṣe ní ìpèbí
  • Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná – Oríadé kan figbe ta

“Ẹ jọwọ, a si nilo iranwọ owo, ẹ ba wa tun fi owo ransẹ fun itọju mama Iyabo Oko, ọra wa ko ni su yin, tiyin naa ko ni su Ọlọrun.

Gbogbo owo tẹ da fun ajọ Para lori Iyabo Oko la gbe silẹ fun wọn lati fi se itọju wọn.”

Labẹlẹ naa si la n gbọ ti mama naa n se adura kikankan fun awọn eeyan to n da owo fun pe wsn ko ni fi oju sunkun ọmọ.

Foluke ni ilu Ibadan ni Iyabo Oko wa, ẹnikẹni to ba si ni ohunkohun to fẹ se fun mama naa, le lọ se abẹwo si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ