Kóótù gba onídùúró Cubana Chief Priest pẹ̀lú mílíọnù mẹ́wàá náírà

Cubana Chief Priest

Lẹyin to loun ko jẹbi pẹlu alaye, ile-ẹjọ ti faaye beeli miliọnu mẹwaa naira silẹ fun Cubana Chief Priest to foju ba kootu lori ẹsun tita abuku owo naira lode ariya

Adajọ Kẹhinde Ogundare to gbẹ ẹjọ naa, paṣẹ pe oniduuro meji ti wọn jẹ ọmọluabi gbọdọ wa fun Cubana.

O ni wọn gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ, awọn oniduuro naa gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba apapọ abi ti ipinlẹ.

Wọn si gbọdọ wa ni ipele kẹrindinlogun lẹnu iṣe, o kere julọ.

Bakan naa ni kootu paṣẹ pe Cubana Chief Priest gbọdọ fi iwe irinna rẹ silẹ fun kootu, wọn ni ko si aaye irinajo fun un lasiko yii.

igbẹjọ mi-in di ọjọ keji, oṣu karun-un ọdun 2024.

Anfaani ọjọ meje ni kootu fun un lati pari eto iduro gbigba naa

Gẹgẹ bi kootu ṣe wi, aaye ọjọ meje wa fun olujẹjọ lati yanju eto gbigba oniduuro yii.

Ki asiko naa too pe ṣaa, ile-ẹjọ fun un lanfaani lati maa lọ sile.

Lọọya to gbẹnusọ fun Cubana Chief Priest, ni wọn fa a le lọwọ pẹlu alaye pe amofin naa yoo tọwọ bọwe lati mu onibaara rẹ wa tọjọ ba pe.

Aworan Cubana Chief Priest

Oríṣun àwòrán, Cubana Chief Priest/Instagram

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti sọ pe awọn yoo fi oju gbajugbaja oniṣowo nni, Pascal Okechukwu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Cubana Chief Priest ba ile-ẹjọ.

Ẹsun ti ajọ EFCC fi kan Cubana Chief Priest ni pe o wa lara awọn to n ṣe owo naira niṣekuṣe, gẹgẹ bi eyi ti wọn fi kan ọdọmọkunrin to n ṣebi obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ile-ẹjọ giga apapọ ju Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lai fi aye silẹ fun owo itanran rara.

Oni tii ṣe Ọjọru ni ajọ EFCC sọ pe Cubana Chief Priest yoo fi oju ba ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Eko lori bo ṣe n fọn owo ka nita gbangba, eyi ti wọn lo tapa si ofin banki agba orileede yii, iyẹn Central Bank Act of 2007.

Nigba to n fidi iroyin mulẹ, Dele Oyewale to jẹ agbẹnusọ ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Cubana Chief Priest, ti awọn yoo si fi oju rẹ ile-ẹjọ.

“Bẹẹni, Cubana Chief Priest ti wa ni ahamọ wa, a si maa fi oju ba ile-ẹjọ l’Ọjọru, ọsẹ yii.”

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2024 ti a wa yii ni agbẹjọro EFCC, Rotimi Oyedepo ati awọn agbẹjọro meje miran ti wọn ṣoju alaga EFCC, Ọla Olukayọde fi ẹsun kan Pascal Okechukwu wi pe o na owo naira loju agbo, ti wọn si tun n tẹ ẹ mọlẹ.

Ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2024 ni wọn sọ pe Pascal ṣe owo naira niṣekuṣe ni otẹẹli Eko (Eko Hotel), eyi ti wọn lo tako ofin banki apapọ lori nina owo naira, to si ni ijiya ninu ni abala kọkanlelogun akọkọ.