Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo da ibùba àwọn ajìjàgbara Oodua Nation wò nílùú Ibadan

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gbe igbesẹ nla lati wo ile ti olori ikọ ajijagbara Oodua Nation, Modupe Abiola Onitiri ti kede ominira Ilẹ Yoruba lọsẹ to kọja niluu Ibadan.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn ikọ ajijagbara Oodua Nation yii lo kọlu ọgba ọfisi gomina ipinlẹ Oyo ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, ti wọn si wa pẹlu ero lati gba ijọba.

Kọmisana feto ilẹ, ile ati idagbasoke nipinlẹ Ọyọ, William Akin-Funmilayo lo fi idi iroyin naa mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nibi ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ti wo awọn ile ti o sapejuwe pe wọn ni ibasepo pẹlu ẹgbẹ awọn afurasi to n ja fun ominira orilẹede Yoruba.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt

Saaju ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kọkọ wo ile kan to wa ni opopona Toye Oyesola, Shagari, to wa ni agbegbe Boluwaji niluu Ibadan ti wọn sọ pe awọn afurasi ajijagbara fun ominira orilẹede Yoruba fi ṣe ibugbe wọn saaju ki wọn to kọlu ọgba ọfisi Gomina Oyo.

Funmilayo ṣalaye fun awọn akọroyin nigba to n mu wọn yika ile naa pe ijọba fa a ile na lulẹ lẹyin to ti gba aṣẹ lọwọ ile-ẹjọ.

“Ojo meji sẹyin ni a gba iwe lati kootu pe a le wo awọn ile ati ibugbe ti awọn afurasi aja fun ominira orilẹede yorubafi ṣe ibugbe ati ibi farapamọ si, ti orisirisi ohun ija oloro bi ibọn, ada ati awọn nkan miran wa ni bẹ”.

Lara awọn olugbe adugbo naa ṣalaye fun Akọroyin Ile iṣẹ BBC Yoruba wi pe lọjọ ti wọn ṣe ikọlu si ile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, adugbo naa ni wọn ti ko ara wọn jọ ninu aṣọ ologun ti wọn si n dun koko mon awọn olugbe adugbo naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt

Aworan

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt

“Nisẹ nì wọn fi ibọn ha lẹ mọ wa ladugbo ki wọn to lọ si Ọfisi ijọba ipinlẹ Ọyọ”

Ara adugbo naa to ni ki BBC Yoruba forukọ bo oun lasiri ṣalaye wi pe awọn afurasi aja fun ominira ile Yoruba sọ wi pe, laarin wakati kan sì akuko ti wọn halẹ mọ awọn olugbe agbegbe naa ni awọn adari ẹgbẹ to n ja fun ominira orilẹede Yoruba kede ominira patapata kuro lara orilẹede Naijiria.

Oni lẹsẹkẹsẹ lawọn kesi awọn ẹsọ alaabo pe awọn afurasi aja fun ominira ilẹ Yoruba ti n morile ṣẹkitariati ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni agbegbe Agodi .

Akin -Funmilayo ni “Ijoba ipinlẹ Ọyọ yoo ṣeto aabo ati ifokanbale fun awọn olugbe ipinle naa ti o si rọ wọn lati tete fi to ijọba leti awọn ohun ti o ku diẹ kaa to ladugbo wọn.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ tun wa rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati maa tete fi to ijọba leti awọn ohun to jẹ ajoji ni awọn agbegbe kowa wọn ki aabo todajule wa.