EFCC kéde Yahaya Bello bí ẹni tí wọ́n ń wá

Àtẹ̀jáde EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC/FACEBOOK

Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC ti kéde gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí EFCC fi sórí FACEBOOK wọn lọ́jọ́bọ̀ ni wọ́n kéde àwọn ń wá Yahaya Bello lórí ẹ̀sùn tó ní ṣe pẹ̀lú kíkó owó ìlú tó lé ní ọgọ́rin bílíọ̀nù náírà jẹ.

Wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ìmọ̀ nípa bí àwọn ṣe lè mú Yahaya Bello ni kó fi tó àwọn létí tàbí kí wọ́n lọ sọ ní àgọ́ ọlọ́pàá tó bá súnmọ́ wọn.

Ṣáájú ni EFCC ti ní àwọn máa lo gbogbo ohun tó yẹ lábẹ́ òfin láti fi pámpẹ́ òfin wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀ rí, Yahaya Bello lọ sí ilé ẹjọ́ láti jẹ́jọ́ lórí ìwà àjẹbánu tí wọ́n fi kàn-án.

Yahaya Bello kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 nígbà tí EFCC wọ lọ sílé ẹjọ́ láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ìwà ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ tí wọ́n fi kàn-án.

Àwọn ọlọ́pàá àtàwọn alátìlẹyìn Yahaya Bello kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ EFCC fi pámpẹ́ òfin mú Yahaya Bello ní ilé rẹ̀ tó wà ní Wuse Zone 4, Abuja.

Agbẹjọ́rò EFCC, Kemi Phinero sọ fún adájọ́ Emeka Nwite nílé ẹjọ́ lọ́jọ́bọ̀ pé àwọn kan tí wọ́n ní òfin aṣẹ̀málù ni wọ́n ń dá ààbò bo Yahaya Bello, tó fi ṣòro láti ri fi sí àhámọ́ àwọn.

Àmọ́ agbẹjọ́rò Yahaya Bello, Abdulwahab Mohammed sọ fún ilé ẹjọ́ pé EFCC kò pe oníbàárà àwọn lẹ́jọ́ bó ṣe tọ́.

Gbogbo ìgbìyànjú agbẹjọ́rò EFCC, Phinero láti fún agbẹjọ́rò Yahaya Bello ní ìwé ìpẹ̀jọ́ náà ló já sí pàbó.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríyànjiyàn, Phinero ní àwọn máa sa gbogbo ipá àwọn láti ri pé àwọn gbé olùjẹ́jọ́ wá sí ilé ẹjọ́ kódà kó jẹ́ pé àwọn máa lo àwọn ọmọ ogun láti fi ri pé àwọn gbé e dé ilé ẹjọ́.

Ó ní kí ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ síwájú láti fi wá ṣàfihàn Yahaya Bello, tí adájọ́ Emeka Nwite sì sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹrin.

Kí ni ìdí tí EFCC fi ń wọ̀dìí Yahaya Bello?

Àtẹ̀jáde tí EFCC fi léde

Oríṣun àwòrán, EFCC/FACEBOOK

Níṣe ni ọ̀rọ̀ dàbí eré orí ìtàgé lọ́jọ́rú ní ilé ìgbé Yahaya Bello tó wà ní Wuse Zone 4, Abuja nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ EFCC fẹ́ fi kélé òfin gbé e.

Àwọn òṣìṣẹ́ EFCC kan ni wọ́n lọ dí ẹnu ọ̀nà ilé Yahaya Bello fún ọ̀pọ̀ wàkátì àmọ́ àwọn ọlọ́pàá kan àtàwọn alátìlẹyìn Yahaya Bello kò jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ EFCC náà wọlé náà láti mú Yahaya Bello.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ sígbà náà, gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Usman Ododo yọjú sí ilé Yahaya Bello tó sì kúrò lẹ́yìn wákàtí díẹ̀.

EFCC padà sọ pé gómìnà Ododo ló wá fi ọkọ̀ gbé Yahaya Bello kúrò nínú ilé náà.

EFCC tún fi kun pé àwọn ní ìwé àṣẹ láti fòfin gbé Yahaya Bello kí àwọn sì gbe lọ síwájú ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owọ ìlú tó lé ní ọgọ́rin bílíọ̀nù náírà kúmọkùmọ.

Ìjókòó ilé ẹjọ́ padà wáyé àmọ́ Yahaya Bello kò yọjú sílé ẹjọ́ bí EFCC kò ṣe ní àǹfàní láti fi sí àhámọ́ wọn lọ́jọ́rú.

Ẹjọ́ tó wà lọ́rùn Yahaya Bello

Ṣáájú ni àjọ EFCC ti pé ẹjọ́ tako àwọn abẹ́ṣinkawọ́ Yahaya Bello mẹ́ta kan tó fi ma ìbátan rẹ̀, Ali Bello lórí ẹ̀sùn kíkọ owó ìlú sápò ara wọn lọ́dún 2022.

Ẹ̀sùn mẹ́wàá tó ní ṣe pẹ̀lú owó bílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni wọ́n kà sí wọn lọ́rùn àmọ́ nígbà tó di oṣù Kejì ọdún 2024, wọ́n fi ẹ̀sùn méje kún mẹ́wàá tí wọ́n kà sí wọn lọ́rùn tẹ́lẹ̀.

EFCC fẹ̀sùn kan pé Yahaya Bello pé ó lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú Ali Bello, Dauda Suleiman àti Abdusalam Hudu láti fi ló owó tó lé ní ọgọ́rin bílíọ̀nù náírà tó jẹ́ owọ ìlú sápò ara wọn àti pé nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2015 ni wọ́n ti ṣẹ̀ṣẹ̀ náà, èyí tó jẹ́ oṣù mẹ́rin kí Yahaya Bello tó di gómìnà Kogi lọ́dún 2016.

Ẹ̀jọ náà ṣì wà níwájú adájọ́ James Omotosho ti ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ Abuja.

Ẹ̀wẹ̀, EFCC ń ka ẹ̀sùn mọ́kàndínlógún mìíràn sí Yahaya Bello lọ́rùn níwájọ́ adájọ́ Emeka Nwite, àwọn ẹ̀sùn náà farajọ èyí tó wà lọ́rùn rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ EFCC wà nílé Yahaya Bello lọ́jọ́rú, ó fi àtẹ̀jáde kan síta pé òun k]o mọ ìdí tí EFCC fi fẹ́ fi ipá mú òun nítorí wọn ò kọ̀wé ránṣẹ́ pé òun láti wá wí tẹnu òun lọ́nà tó tọ́.

Ó ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kogi lóṣù Kejì ọdún 2024 ti dènà EFCC láti fi òun sí àhámọ́ tàbí tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú mọ́lẹ̀ títí tí wọ́n fi máa gbọ́ ẹjọ́ òun tó wà nílé ẹjọ́ náà tán.

Ó ní òun k]o mọ ìdí tí EFCC, tí ọ̀gá rẹ̀ jẹ́ amòfin, fi ń tẹ àṣẹ ilé ẹjọ́ lójú mọ́lẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tó bá dènà àwọn òṣìṣẹ́ wa lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ wọn yóò fi ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún gbára – EFCC

Aworan ileese EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC/’X’

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission ti sọ pe ẹnikẹni to ba gbiyanju lati di awọn oṣiṣẹ wọn lọwọ lati ṣiṣẹ wọn yoo fi ẹwọn ọdun marun gbako gbara.

EFCC lo sọ eyi di mimọ lawọn oju opo ayelujara wọn bii Twitter ati Facebook laipẹ yii, ti wọn si lawọn ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn to n dina mọ iṣẹ wọn mọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Dele Oyewale buwọ lu, o ni ẹsun ọdaran ni ki ẹnikẹni di oṣiṣẹ EFCC lọwọ lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ wọn lọwọ.

Oyewale ni abala kejidinlogoji (Section 38(2)(a(b)) to wa ninu iwe ofin idasilẹ EFCC jẹ ko di mimọ pe ẹṣẹ nla ni fun ẹnikẹni lati dena oṣiṣẹ ajọ naa lasiko ti wọn ba fẹ ṣiṣẹ wọn.

Bẹẹ lo sọ pe ninu abala naa lo tun wa pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ yoo fi ẹwọn ọdun marun gbako gbara.

Bi ẹ ko ba gbagbe, l’Ọjọru, ọsẹ yii ni ajọ naa gbiyanju lati fi kele ofin gbe gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ṣugbọn ti a gbọ pe ikọ ẹṣọ aabo lo dena wọn.

Oyewale ni o ti n di lemọlemọ araalu lati maa dena EFCC lati mu awọn ti aje ọrọ iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori, to si di dandan pe ki awọn ṣe iwadii.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe lati asiko yii lọ, ajọ naa ko nii gba awọn to ba fẹẹ dena wọn lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ mọ.

EFCC yóò fi ojú Yahaya Bello ba ilé-ẹjọ́ lónìí lórí ẹ̀sùn lílu owó ìlú ní póńpó

Aworan EFCC ati Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, EFCC ati Yahaya Bello/Others

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti sọ pe awọn yoo fi oju gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Adoza Bello ba ile-ẹjọ lonii.

Oni ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2024 lori ẹsun ṣiṣe owo to le diẹ ni ọgọrin biliọnu owo naira mọkumọku.

EFCC lo fi eyi lede lopo ayelujara ti Instagram wọn l’Ọjọru, ọsẹ yii, ti wọn si ni ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abuja l’awọn yoo fi oju rẹ ba.

Eyi ko ṣai waye pẹlu bi ajọ EFCC ṣe sọ pe awọn gba aṣẹ ile-ẹjọ lati fi ofin gbe Yahaya Bello l’Ọjọru, ọjọ kẹtadinlogun, oṣukẹrin, ọdun 2024.

Bakan naa ni ajọ EFCC tun jẹ ko di mimọ pe iwaju Onidajọ Emeka Nwite ni Yahaya Bello ati awọn mẹrin miran ti wọn fẹsun kan yoo ti kawọ pọyin rojọ.

Awọn mẹta naa ni Alli Bello, Dauda Suleiman ati Abdulsalam Hudu.

Ẹsun mọkandinlogun ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ṣiṣe owo ilu to le diẹ ni ọgọrin biliọnu (N80, 246, 470, 088.88) mọkumọku.

Skip Instagram post

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.