Kókó mẹ́fà tí Tinubu àtàwọn gómìnà fẹnukò lé láti mú àdínkù bá ọ̀wọ́n gógó

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/FACEBOOK

Ààrẹ Bola Tinubu àtàwọn gómìnà mẹ́rìndínlógójì tó wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ṣe ìpàdé láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ọ̀wọ́n gógó tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra lásìkò yìí.

Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Kejì ni ìpàdé náà wáyé ní ilé ààrẹ tó wà ní Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Níbi ìpàdé náà ni wọ́n ti fẹnukò lórí àwọn nǹkan tó ṣe kókó àti àwọn ìgbèsẹ́ tí ìjọba nílò láti gbé, kí àdínkù le bá ìṣòro tí àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí ń kojú nítorí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti àìsí ètò ààbò tó péye.

Lẹ́yìn tí wọ́n foríkorí ni wọ́n gbé ìpinnu mẹ́fà kalẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro náà.

Àwọn kókó ti Tinubu àtàwọn gómìnà fẹnukò lé lórí nìyí:

  • Lórí ètò ààbò, ààrẹ Tinubu ní òun ti ní kí wọ́n gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí yóò rí sí ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ dípò àwọn fijilanté tí ọ̀pọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ gbójúlé láti kojú ìṣòro ètò ààbò.
  • Ààrẹ ní àwọn máa ṣàrídájú rẹ̀ pé àwọn gba àwọn ọlọ́pàá kún àwọn èyí tó ti wà tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìpèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe kókó fún wọn láti kojú ìpèníjà tó wà lóde.
  • Bákan náà ni ààrẹ tún ní kí àwọn gómìnà ró àwọn aṣọgbó káàkiri ìpínlẹ̀ wọn lágbára si ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí wọ́n sì fún wọn ní àwọn ohun ìjà kí wọ́n lè kojú àwọn ajínigbé tó ń fi àwọn igbó ṣe iṣẹ́ láabi wọn.
  • Lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ, Tinubu darí àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ láti ṣiṣẹ́ papọ̀ lójúnà àti ri pé àwọn àgbẹ̀ pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.
  • Ààrẹ ni òun kò ní fọwọ́ si kí wọ́n kó oúnjẹ wọlé láti ilẹ̀ òkèrè tàbí gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí yóò mójútọ iye tí wọ́n yóò máa ta ọjà. Ó ní dípò bẹ́ẹ̀ òun tí òun yóò ṣe ni ríró àwọn àgbẹ̀ Nàìjíríà lágbára láti pèsè oúnjẹ ju bí wọ́n ṣe ń pèsè rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ.
  • Tinubu tún gba àwọn gómìnà náà ní ìmọ̀ràn láti mójútó bí àwọn kan ṣe ń kó oúnjẹ pamọ́ láti máa tà wọ́n ní owó gegege.
  • Ó pa á láṣẹ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ DSS àti ọ̀gá ọlọ́pàá láti ri dájú pé wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ilé ìtajà tí wọ́n ń kó oúnjẹ pamọ́ dípò títà wọ́n fún aráàlú.
  • Ó fi kun pé àwọn gómìnà nílò láti mójútó àwọn nǹkan ọ̀sìn tí wọ́n ń pèsè ní ìpínlẹ̀ wọn tó fi mọ́ ìpèsè ẹja àti àwọn adìyẹ.
  • Bákan náà ló tún rọ àwọn gómìnà náà láti san owó oṣù tí wọ́n jẹ àwọn òṣìṣẹ́ kí owó lè tó wọn-ọn ná, pàápàá bó ṣe jẹ́ pé owó tí àwọn ìpínlẹ̀ ń rí gbà láti ọdọ̀ ìjọba àpapọ̀ ti lé kún si.
  • Bẹ́ẹ̀ náà ló tún rọ̀ wọ́n láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀ ajé wọn.