Taa ni Oyetunde Ojo, ọkọ ọmọ Ààrẹ Tinubu tó di alága àjọ FHA

Tinubu and Oyetunde Oladimeji Ojo

Oríṣun àwòrán, Oyetunde Oladimeji Ojo/Facebook

Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti kede ọkọ ọmọ rẹ, Oyetunde Ọladimeji Ojo gẹgẹ bii alakoso agba fun ileeṣẹ Federal Housing Authority (FHA).

Ojo to ti figba kan ri jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to ṣoju ẹkun Ekiti West, Ijero ati Ẹfọn, ipinlẹ Ekiti niluu Abuja ni Aarẹ Tinubu kede rẹ l’Ọjọbọ, ọsẹ yii.

Ninu atẹjade ti oludamọran pataki lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Ajuri Ngelale gbe sita, lo ti ni iṣẹ Ojo ati awọn ọmọ igbimọ iṣakoso miran to kede wọn bẹrẹ loju ẹsẹ lai fi asiko ṣofo.

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun buwọ lu igbimọ iṣakoso Federal Mortgage Bank of Nigeria (FMBN) ti alakoso agba ati oludasilẹ rẹ jẹ Shehu Usman Osidi.

Ojo ni kẹkọọ gboye Masters Degree nipa imọ Peace and Conflict Studies ni fasiti Greenwich to niluu United Kingdom.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 1979 ni wọn bi Ọnarebu Oyetunde Ọladimeji Ojo, to si lọ si ile-ẹkọ alakọbẹrẹ.

Ọdun 1988 ni Ojo lọ sile-ẹkọ girama ti Senton, to si ṣetan lọdun 1994.

Ojo ni imọ ẹkọ nipa iṣẹ iroyin, bẹẹ lo tun kẹkọọgboye nipa imọ eto oṣelu laarin ọdun 2002 si 2005.

Ogbontarigi oniṣowo naa jẹ alaga eto ikansira-ẹni, igbogun ti iwa jibiti ati ileeṣẹ National Ethics & Value Industries lasiko to wa nipo ọmọ ile igbimọ aṣofin.

Ojo jẹ ọkọ ọmọ Aarẹ Tinubu, Arabinrin Fọlaṣade Tinubu-Ojo to jẹ Iyalọja tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan nipinlẹ Ekoo lẹyin ti iyalọja ana papoda.