Ìwádìí tí tú àṣírí bí ọlọ́pàá àti ológun ṣé n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú-Gómìnà El Rufai

Aworan Gomina El Rufai

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El Rufai ti sọ pe esi iwadii tawọn ṣe kan ti fi han pe awọn ọlọpaa n lẹdi apo pọ pẹlu awọn janduku to n da omi alaafia ilu ru.

Yatọ si awọn ọlọpaa yi, El Rufai sọ pe awọn ọga ologun kanna lọwọ ninu iwa yi .

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba aarẹ lo ti fi idi ọrọ yi mulẹ.

O ṣalaye pe iwadii fi han pe awọn ọga agbofinro yi n lẹdi apo pọ pẹlu awọn janduku to n da araalu laamu yi.

Amọ o ni ijọba ko ti ni ẹkunrẹrẹ ẹri lati fidi iwadii wọn mulẹ. O sọ pe ọpọ iṣẹ lawọn ni lati ṣe lori ọrọ yi.

Aworan Gomina El Rufai

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

O ni ”o jẹ wa logun o si ṣeeṣe ki wọn lawọn ti wọn jijọ n ṣiṣẹ pọ.Bi mo ṣe tka nigba ti mo n dahun ibeere rẹ, iwadii fi han pe ajọṣepọ wa laarin awọn Boko Haram ati janduku to si tun tọka si pe awọn ọga ọlọpaa ati ologun kan maa n ba awọn janduku yi sọrọ papọ”

”Tori naa a ko le fẹẹku pe ko ni si awọn to n ṣofofofawn aalaburu yi.Amọ titi di oni a ko ti ri ẹri aridaju.Iṣẹ ṣi pọ fun wa lati ṣe.”

Ipenija janduku ati Boko Haram peleke ni Naijiria

Ninu awọn ipenija aabo to n koju Naijiria la ti ri awọn adigunjale,janduku ajinigbe, ọdaran darandaran to fi mọ awọn ajinigbe pawo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ni ipinlẹ Kaduna, ipenija aabo j eleyi to ti wa tipẹ.

Bi wọn ko ba maa koju ija ẹlẹyamẹya tabi ija laarin awọn musulumi ati Kristeni, ijinigbe ati ikọlu janduku jẹ ohun to tun jẹ ipenija fun ipinlẹ naa.

Bi a ko ba gbagbe, iroyin gbode laipẹ yi pe awọn ajinigbe janduku ti wn le kuroloju ọna Kaduna si Abuja tun ti bẹrẹ iṣẹ pada ti wọn si ṣeku pa

Eleyi nikan kọ, awọn janduku a maa yabo ile ẹkọ ti wn a si tun maa ji awọn akẹkọọ gbe lai fi ti ọjọ ori wọn ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gomina Nasir El Rufai tipinnu pe ohun ko ni san owo idoola ẹmi fun ẹnikẹni ti awọn ajinigbe ba ji gbe paapa awọn akẹkọọ.

O sọ pe bi ijọba ba fi le san owo fun awọn alaburu yi, wọn yoo sọ di oju ọwọ ni.