Bàbá mi fọwọ́ rọrí kú ni – ọmọ Rotimi Akeredolu ṣàlàyé lórí ikú bàbá rẹ̀

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, x/Rotimi Akeredolu

Ọkan lara awọn ọmọ Gomina Rotimi Akeredolu to d’oloogbe, Oluwarotimi Akeredolu Jnr, ti ṣalaye bi baba rẹ ṣe mi eemi ikẹyin.

Ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ẹbi wọn, eyi to tẹ BBC lọwọ, Ọgbẹni Akeredolu Jnr, sọ pe oju orun ni baba oun gba de oju iku

Ọgbẹni Akeredolu sọ pe wọrọwọ ni gomina naa ku lasiko to n sun, nileewosan kan niluu Germany nibi to ti n gba itọju fun aisan jẹjẹrẹ inu koropọn ọkunrin.

“Bo tilẹ jẹ pe iku rẹ jẹ ibanujẹ fun wa, a ri itunu gba ninu idaniloju pe o ti lọ si ayeraye, nibi ti ọwọ aanu awọn angẹli imọlẹ, to ba gbe nigba to wa ninu aye, yoo ti ṣe amọna rẹ.”

O ṣapejuwe baba rẹ gẹgẹ bi ẹni to ni igboya, to si tun jẹ ẹlẹyinju aanu.

Bakan naa ni Ọgbẹni Akeredolu Jnr sọ pe ẹbi, ati ijọba ipinlẹ Ondo, yoo kede bi eto isinku yoo ṣe waye nigba ti akoko ba to.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Ondo na ti kede iku Gomina Rotimi Akeredolu lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ni.

Kini ijọba ipinlẹ Ondo sọ pe o pa Gomina Akeredolu?

Lati aarọ Ọjọru ti iroyin iku gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti gba ori ayelujara kan lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii nipa ohun to ṣeku pa a ati ibi ti o ku si gan an.

Ọpọ ileeṣẹ iroyin atawọn eeyan kan lo ti n sọ pe ilu Eko ni o ku si, koda awọn kan tun sọ pe niṣe wọn n wa ẹrọ ”dialysis” ti wọn maa fi n ṣe itọju awọn to ba ni arun jẹjẹrẹ kaakiri ilu Eko ki ẹlẹmii too gba a.

Amọ, ijọba ipinlẹ Ondo ti tan imọlẹ si ọrọ naa pẹlu atẹjade ti wọn fi sita lori iku Akeredolu.

Ninu atẹjade ti Bamidele Ademola-Olateju, Kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Ondo, fi sita, o ni gomina Akeredolu fọwọ́ rọri ku ni owurọ kutukutu Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023.

“Gomina Akeredolu jẹ ipe ayeraye nibi to ti n gba itọju ni orile-ede Germany.

“O ku nitori aisan jẹjẹrẹ to mu ni koropọn.”

Arabinrin Ademola-Olateju sọ pe awọn ti kọ lẹta ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu, lati fi iroyin iku gomina to o leti.

O ni awọn yoo kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ.

Bakan naa ni o ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi adari to yatọ, to si fi ọkan ṣiṣẹ sin ipinlẹ Ondo ati awọn eniyan rẹ.

O ni ibanujẹ ti iku rẹ mu wa jẹ ẹru to wuwo lati gbe.

Àwọn eekan ilu daaro Rotimi Akeredolu

Oniruuru awọn eekan ilu lo ti n ṣe idaro gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, SAN, to d’oloogbe.

Owurọ Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Gomina Akeredolu ku, lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.

Ṣaaju iku rẹ, Akeredolu wa ni idubulẹ aisan fun ọpọlọpọ oṣu, eyi to mu ko pada fa iṣakoso ipinlẹ Ondo le igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa, lọwọ.

Rotimi duro bi akin lati koju awọn oniṣẹ okunkun nigba ti wọn ṣọṣẹ kaakiri orilẹede Naijiria – Aarẹ Tinubu

Aarẹ Tinubu pẹlu Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, X/Bayo Onanuga

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu pẹlu ṣe idaro gomina Rotimi Akeredolu to jade laye.

Ninu atẹjade ti aarẹ fi sita, o ni ibaṣepọ oun pẹlu Akeredolu kọja ti oṣelu, nitori pe “arakunrin mi lo jẹ”.

Aarẹ Tinubu ṣapejuwe Gomina Akeredolu gẹgẹ bi ẹni ti kii bẹru lati ja fun ayipada to dara fun ilu.

Aarẹ Tinubu ni o ṣoro lati fi ọrọ ṣe akojọpọ igbe aye Amofin Akeredolu nitori awọn ipa ribiribi to ko ninu “sisun orilẹede Naijiria si ipa iṣọkan, idajọ ododo pẹlu bi o ṣe dide tako gbogbo iwa irẹnijẹ nipa lilo irinṣẹ ofin gẹgẹbi amofin agba fun ipinlẹ, aarẹ ẹgbẹ awọn amofin lorilẹede Naijiria ati gẹgẹbi gomina ipinlẹ Ondo”.

“Rotimi jẹ eniyan to kun fun ọpọlọpọ ọgbọn inu ati ijafafa. Ni igba aye rẹ, o kọ wa bi a ti ṣe n l o agbara fun iṣiṣẹsin araalu.”

Aketi ja ija rere, o si ti pari ire ije rẹ daradara – Akinwunmi Adeshina, aarẹ banki idagbasoke ilẹ Afirika

Aworan Akeredolu ati Adeshina

Oríṣun àwòrán, X/Akinwunmi A. Adesina

Ẹlomiran to tun ti daro Akeredolu ni aarẹ banki idagbasoke ilẹ Africa, Femi Adeshina.

Femi Adeshina ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi akinkanju eeyan, ẹlẹyinju aanu, to sin awọn eniyan rẹ bo ṣe tọ

Ọjọgbọn Akinwumi Adeshina ni Aketi ja ija rere o si pari ire ije rẹ daradara. O ṣe akawe rẹ gẹgẹ bi ọlọkan anu ti o ṣiṣẹ sin awọn eeyan rẹ pẹlu ifọkansin

Aye ọpọlọ pipe ati ẹmi ifọkansin ti Akeredolu fi silẹ yoo nira lati di – Ifeanyi Okowo, gomina ana ni ipinlẹ Delta ni

Lara awọn to tun daro gomina ọhun ni gomina ipinlẹ Delta tẹlẹ, to tun dije fun ipo igbakeji aarẹ lọdun 2023 lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, Ifeayi Okowa.

Ninu atẹjade rẹ loju opo ayelujara X rẹ, gomina ana ni ipinlẹ Delta, Arthur Okowa ṣalaye pe iku rẹ jẹ adanu nla fun orilẹede Naijiria.

O ni akọni ti ko ṣe e fi ṣere paapaa pẹlu ẹmi ifọkansin, igboya ati ọgbọn inu rẹ jẹ eyi ti ko lẹlẹgbẹ rara.

Aworan akọsilẹ Okowa lori ayelujara X

Oríṣun àwòrán, screenshot

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun naa ti fi ibanujẹ han lori iku akẹẹgbẹ rẹ to ku. O sọ loju opo Twitter rẹ pe iranti Rotimi Akeredolu ko le e parun, nitori pe o jẹ awokọṣe fun ireti.

“Iranti rẹ jẹ eyi to kun fun aanu, idajọ ododo, ati ilọsiwaju, to jẹ awọn awokọṣe fun adari to ni ẹmi ifọkansin.”

Yatọ si awọn ti a ti mẹnuba, alaga fun ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, to tun jẹ gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, sọ pe ibanujẹ ni iku gomina ipinlẹ Ondo jẹ fun oun.

Ninu atẹjade ti akọwe rẹ, Rafiu Ajakaye, fi sita, Gomina AbdulRasaq awọn ipa rere ati iṣẹ ribiribi ti Akeredolu ṣe nigba aye rẹ, ni yoo jẹ “itunu fun wa’ bo tilẹ jẹ pe ibanujẹ ni iku rẹ jẹ.

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde naa ti fi ibanujẹ ọkan rẹ han lori iku akẹẹgbẹ rẹ.

Makinde sọ pe iku rẹ ti mu ki oun padanu ẹni ti awọn jọ n jija gbara fun ẹkun Iwọ-oorun Gusu Naijiria.

O ni ẹkun naa padanu adari to ni igboya, to si ṣiṣẹ fun alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke rẹ.