Kí ló dé tí Taliban fí fòfin dè kí àwọn obìnrin máa dá rírìn àjò tó bá ti jiná?

Awọn obinrin ẹlẹha ninu ọkọ ninu ọkọ ni Kandahar lọjọ Kejidinlogun oṣu Kejila

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba Taliban lorileede Afghanistan ti fofin de kawọn obinrin maa da rinrinajo toba jina ayafi ti mọlẹbi ọkunrin ba tẹle wọn.

Aṣẹ yi ti wọn fi sita lọjọ Aiku wa lara na ti dena ẹtọ awọn obinrin eyi ti wọn bẹrẹ lati igba ti wọn gba ijọba loṣu kẹjọ.

Ọpọ awọn ileẹkọ girama ṣi wa ni titipa fawọn obinrin ti wọn o si faaye gba kawọn obinrin ṣiṣẹ.

Ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan Human Rights Watch sọ pe ilana tuntun yi jẹ ọna ati sọ awọn obinrin di ẹlẹwọn.

Heather Barr, to jẹ oludari eto ẹtọ awọn obinrin sọ fun AFP pe ”aṣẹ yi gbegi dina anfaanni to wa fawọn obinrinlati le rin kaakiri lai si idiwọ tabi lati le sa ti ijiya ba pọ fun wọn ninu ile”

Ileeṣẹ to n mojuto itẹsiwaju iwa daada ati igbogun ti aburu sọ pe obinrin to ba n rinrinajo to kọja mẹẹli marundinlaadọta gbọdọ ni mọlẹbi ọkunrin ti yoo tẹlẹ

”Inu mi ko dun si” ni ọrọ ti arabinrin Fatima to jẹ iyawo ile ton gbe Kabul sọ fun BBC ni idahun si aṣẹ tuntun yi.

”Mi o le danikan jade.Ki ni maa ṣe ti o ba rẹ eni tabi ọmọ mi ti ọkọ miko si si nile?”

O fiun pe ”awọn Taliban gba idunnu lọwọ wa…Ati idunnu ati ominira mi ni moti padanu”.

Ofin taa n wi yi kesi gbogbo awọn awakọ latima se gbe obinrin ti koba wọ Hijab tabi iboju botilẹjẹwi pe wọn ko sọ iru iboju to yẹ ki wọn lo.

Pupọ awọn obinrin Afghanistan ni wọn n bori wọn.

Ofin yi tun fofin de ki wọn maa kọ orin ninu ọkọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn obinrin ẹlẹha ni Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati igba ti Taliban ti gba ijọba lẹyin ti awọn ọmọ ogun Amẹrika pal ẹru wọn mọ, wọn sọ fun awọn obinrin lati joko sile ti wọn si si ile ẹkọ girama silẹ fawọn ọkunrin nikan pẹlu olukọ ọkunrin.

Taliban sọ pe awọn ofin idiiwọ yi ko ni lọ titi ati pe awọn gbe kalẹ ki wn baa le daabo bo obinrin ni.

Lasiko ti wọn ṣe ijba kọja wọn kọdi ki awọn obinrin kẹkọ tabi ki wọn ṣe iṣẹ.

Loṣu to kọja ni wọn fofin de ki awọn obinrin kopa ninu ere tiata lori ẹrọ amounmaworan.

Wọn tun paṣẹ pe ki awọn atọkun lori tẹlifisọn maa wọ ibori tabi sikaafu.

Awọn orileede to fẹ se iranwọ fun Afghanistan ti sọ pe awọn ko ni ṣe bẹ ayafi ki Taliban da ẹtọ awọn obinrin pada.

Orileede naa n koju ipenija ọrọ aje to mẹhẹ nitori bi iranwọ ko ṣe si fun wọn lati igba ti Taliban ti gba ijọba.