Ǹkan tí mo fẹ́ ni kí wọ́n sunkún nílé àwọn tó pa abúrò mi náà torí wọ́n pa wá lẹ́kún – Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ó ti pé oṣù kan àti ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n bá òkú arákùnrin kan Timothy Adégòkè ní ilé ìtura Hilton Hotel ní Ilé-Ifẹ̀, ẹjọ si ti n lọ lori rẹ lati igba naa gẹgẹ bi ẹbi ko ṣe fẹ ki wọn jẹ ẹ mọlẹ.

Mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, àti àwọn ọ̀dọ́ Ìbàràpá ni wọ́n dìde láti ṣe fífi ẹ̀hónú hàn lórí ikú tó pa arákùnrin náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn ọ̀dọ́ náà ni ìdájọ́ òdodo gbọdọ̀ jẹyọ nínú ìwádìí àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyé tí kò sì gbọ́dọ̀ sí fífi ọwọ́ ọlá gbá’ni lójú láti ọ̀dọ àwọn afurasí tó wà ní àhámọ́ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyé.

Nínú ìf’ọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n olóògbé, Adégòkè Olúgbadé ni Ìdájọ́ òdodo ni àwọn ń fẹ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba fún àwọn tó ṣe ikú pa àbúrò òun àti’pé àwọn afurasí náà gbọ́dọ̀ f’ara bá òfin nítorí wọ́n’ ṣe ikú pa ògo ìdílé àwọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lara awọn eekan to ti wa nibi iwọde naa ni Oriyomi Hamzat to jẹ ọkan lara awọn adari ẹsin Islam ni ilu Eruwa, ẹgbọn Timothy to n ṣoju idile ati awọn to ṣe agbatẹru iwọde ọhun.

Kọmireedi Sunday Ògúnjìmí pẹ̀lú darapọ àwọn ọ̀dọ́ Ìbàràpá tí’wọ́n parapọ̀ láti fi ẹ̀hónú hàn ní ìlú Ẹ̀rúwà láti rí wípé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ọ̀rọ̀ ikú Timothy Adégòkè.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ẹgbọn